Wọn tun mu tọkọ-taya kan pẹlu ẹya ara eeyan loriṣiiriṣii l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Pẹlu bi ọrọ ọmọ ti wọn ge ori ẹ lati fi ṣetutu owo ko ṣe ti i kasẹ nilẹ l’Abẹokuta, awọn tọkọ-taya kan tun ree tọwọ ba lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila, oṣu keji, ọdun 2022 yii. Ẹya ara eeyan oriṣiiriṣii lawọn ọlọpaa ba lọwọ wọn l’Abẹokuta kan naa.

Aarọ ọjọ Satide naa ni Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fiṣẹlẹ yii sita ninu atẹjade kan. Oyeyẹmi ṣalaye pe Kẹhinde Ọladimeji; ẹni ọdun mẹtalelogoji ( 43), ni ọkunrin to gbe ẹya ara eeyan oriṣiiriṣii sile naa n jẹ, Adejumọkẹ Raji, ẹni ọdun marundinlogoji (35), si ni iyawo rẹ ti wọn jọ mọ nipa awọn ẹya ara naa.

O tẹsiwaju pe Ojule kejilelaaadọrin, MKO Abiola Way, Lẹmẹ, l’Abokuta, ni wọn n gbe, ati pe Baalẹ Lẹmẹ, Oloye Moshood Ogunwọlu, lo lọọ fi to wọn leti ni teṣan ọlọpaa Kemta, pe ọkan ninu awọn to n gbe nile tawọn tọkọ-tiyawo yii n gbe, iyẹn Pasitọ Adisa Ọlarewaju, lo waa sọ foun pe oun n gbọ oorun buruku kan to n jade lati inu ile awọn tọkọ-taya Raji, oun si fura si wọn.

Eyi ni DPO Kemta, CSP Adeniyi Adekunle ṣe tete ran awọn ọtẹlẹmuyẹ lọ sile naa, nibi ti wọn ti yẹ yara awọn Raji wo, ti wọn si ba ike kan ti ẹya ara eeyan oriṣiiriṣii to ṣi tutu wa ninu ẹ. Bi wọn ṣe mu wọn niyẹn.

Nigba ti wọn n fọrọ wa awọn tọkọ-taya Raji lẹnu wo, wọn jẹwọ pe iṣẹ babalawo lawọn n ṣe. Wọn ni awọn ẹya ara eeyan to wa ninu ike naa ni ọwọ, ọyan, atawọn ẹya ara mi-in loriṣiiriṣii. Wọn ni ẹnikan to n jẹ Michael, to n gbe l’Adatan, l’Abẹokuta, lo gbe e fawọn.

Ṣugbọn ko sẹni to gburoo Michel ọhun, nitori awọn tọkọ-tiyawo yii ko le tọka ibi to n gbe l’Adatan.

Kinni kan tawọn ọlọpaa tun sọ ni pe ni nnkan bii ọsẹ kan sẹyin ni awọn ri oku eeyan kan ti wọn ti ge awọn ẹya ara rẹ kan kuro, wọn ni nibi ira kan lawọn ti ri i ni Lẹmẹ. Boya oku ẹni ti wọn waa ri ninu ira naa lawọn Raji gbe si yara yii tabi bẹẹ kọ, awọn ọlọpaa sọ pe awọn naa ko ti i le sọ.

Ṣugbọn ṣa, CP Lanre Bankọle ti i ṣe ọga ọlọpaa Ogun, ti ni ki wọn gbe awọn tọkọ-tiyawo yii lọ sẹka to n ri si ipaniyan fun iwadii lẹkun-unrẹrẹ.

Ọga ọlọpaa yii ṣeleri pe ẹnikẹni to ba lọwọ ninu iṣẹlẹ yii lọna kan tabi ikeji yoo bọ sọwọ ofin ṣaa ni, yoo si jiya to tọ si i, ko le baa jẹ ẹkọ fawọn oniṣẹ ibi ti wọn ko fẹẹ jawọ ninu iwa ika hihu.

Leave a Reply