Wọn yọ MC Oluọmọ nipo alaga ẹgbẹ onimọto Eko bii ẹni yọ jiga

Faith Adebọla, Eko

Igbimọ alakooso apapọ ti juwe ọna ile fun Ọgbẹni Musiliu Akinsanya tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ onimọto NURTW nipinlẹ Eko, wọn ni ko lọọ rọọkun nile na, titi di ọjọ mi-in ọjọ ire.

Ninu lẹta kan ti wọn kọ si MC Oluọmọ, eyi ti ẹda rẹ tẹ ALAROYE lọwọ, wọn pe akori lẹta naa ni iyọnipo ti ko lọjọ (Indefinite Suspension), ti Akọwe apapọ ẹgbẹ National Union of Road Transport Workers (NURTW), Alaaji Kabiru Ado Yau, buwọ lu, lorukọ igbimọ alakooso apapọ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹta, ọdun 2022.

Lẹta naa kan lapa kan pe:

“Eyi ni lati sọ fun ọ pe gẹgẹ bii abala kejilelogoji, isọri karun-un iwe ofin ẹgbẹ NURTW ṣe sọ, a ti yọ ọ nipo alaga ẹgbẹ NURTW, ẹka ti ipinlẹ Eko, titi di ọjọ mi-in ọjọ ire, bẹrẹ lati ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹta, ọdun yii.

“A yọ ọ nipo yii, latari bo o ṣe n tapa sofin ẹgbẹ, to o n huwa ta-ni-maa-mu-mi, o ri awọn agbaagba ẹgbẹ apapọ fin, o si tun n huwa to n tanna ran rogbodiyan ati laasigbo laarin ẹgbẹ onimọto Eko, latari bo o ṣe kọ lati tẹle aṣẹ ti igbimọ alakooso apapọ pa fun ọ lolu-ile ẹgbẹ l’Abuja, lọjọsi.

“Iwa to o hu yii ti jin iṣọkan ati alaafia to wa laarin ẹgbẹ naa lẹsẹ nipinlẹ Eko, o si ṣee ṣe ko ṣakoba fun alaafia ati aabo awọn olugbe Eko, eyi ti ẹgbẹ wa ko fara mọ rara, idi ree ta a fi ni lati gbe igbesẹ pato yii lodi si ọ.

Ma gbagbe pe igbimọ yii kọwe waa-wi-tẹnu-rẹ si ọ lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ati lọjọ kẹta, oṣu Kẹta yii kan naa, ṣugbọn niṣe lo fi ẹgbẹ gun lagidi, to o si kọ lati fesi ibeere wa.

“Pẹlu iyọnipo yii, a paṣẹ fun ọ lati fa akoso ẹgbẹ NURTW Eko le Igbakeji alaga lọwọ, ko o si ko gbogbo dukia ẹgbẹ to ba wa nikaawọ rẹ fun Akọwe ẹgbẹ ni waranṣeṣa.”

Bẹẹ ni lẹta naa ṣe ka.

 

Leave a Reply