Yahaya Bello takete, o loun ko ni i ba wọn gba owo-ori ọja ni toun

Adefunkẹ Adebiyi

Ọrọ owo-ori ọja (VAT) ti ipinlẹ Eko ati Rivers lawọn fẹẹ maa gba, ti wọn ni kijọba apapọ yee yan awọn jẹ, ko ri bẹẹ lọdọ Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello.

Ọkunrin naa ni oun ko ni i ba wọn gba a ni toun, o ni ijọba apapọ to n gba a naa ni yoo maa gba a lọ.

Kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ Kogi, Ọgbẹni Kingsley Fanwo, lo sọ eyi di mimọ ninu ifọrọwerọ kan ti wọn ṣe fun un nileeṣẹ tẹlifiṣan Arise, lọjọ Ẹti, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹsan-an ọdun 2021.

Fanwo sọ pe, “Ọlọrun ko da wa dọgba, Ọlọrun to dẹ da wa ko pin arisiki wa dọgba, a si gbọdọ maa ran ara wa lọwọ ni.

“Ohun ti wọn fẹẹ maa ṣe yii fi han pe awọn aṣiwaju wa kan ki i ro ti ara yooku rara, adanikanjẹ wa fun wọn, wọn si fẹẹ maa ṣe awọn ofin ti yoo tubọ maa pin orilẹ-ede yii yẹlẹyẹlẹ ni”

Kọmiṣanna yii tẹsiwaju pe to ba jẹ pe ipinlẹ Kogi fẹẹ ya anikan-jẹ-ọpọn ni, ilu naa gan-an lo yẹ ko maa ja fun owo-ori ọja yii ju, pe awọn ko ni i jẹ kijọba apapọ gba a mọ.

O ni ipinlẹ bii mẹwaa ni Kogi jẹ aala fun, ẹnu ibode lo jẹ fun ilẹ Hausa, Guusu ati ibi gbogbo ni Naijiria yii, ẹgbẹẹgbẹrun mọto lo si n na oju ọna awọn lojumọ, ile-aje ni Kogi jẹ fun Naijiria, awọn lo si yẹ kawọn maa ja fun owo-ori ọja yii to ba jẹ awọn ko nifẹẹ Naijiria ni.

O ni ṣugbọn Yahaya Bello ki i ṣeeyan bẹẹ, ko fẹran keeyan nifẹẹ ara ẹ ju ara yooku niluu rẹ lọ, iyẹn lo ṣe jẹ awọn ko ni i gba owo ele ori ọja, kijọba apapọ maa gba a lọ bii iṣe wọn, ki wọn maa fun Kogi niye ti wọn ba fẹẹ fun un.

Fanwo ko ti i dakẹ, o ni ṣebi Cocoa House nilẹ Yoruba n ṣe anfaani fun gbogbo Naijiria titi doni, bẹẹ naa si ni ẹpa rẹpẹtẹ ti wọn fi n ṣe ọrọ nilẹ Hausa, ti wọn n pe ni Pyramid, ṣi n pese fawọn eeyan titi doni, nitori wọn ki i ṣe aladaajẹ ni. Wọn fẹ ki awọn eeyan yooku naa jẹ lara wọn, paapaa awọn ti ko ni. Fun idi eyi, o ni Kogi ko ni i bawọn gba ele ori ọja, ti ijọba apapọ ni.

Ṣugbọn latigba ti Kọmiṣanna yii ti sọrọ naa lawọn eeyan ti n bu Gomina Yahaya Bello bii ẹni layin.

Wọn ni bi ko ba jẹ pe gomina naa ko ni arojinlẹ, ko ni i laju silẹ ki gbogbo owo to n ti ilu ẹ wa maa bọ sọwọ ijọba apapọ, ki wọn waa maa fi ṣẹnji gun un lọwọ.

Wọn ni Ọlọrun ko da wa dọgba loootọ, ṣugbọn ko da wa pe ki gbogbo eeyan gọ, paapaa, ẹni to ba jẹ aṣiwaju ilu bii Yahaya Bello yii.

Leave a Reply