Faith Adebọla, Eko
“O ti debi ti oloogun gbe n sa a bayii nilẹ Yoruba. Ko si kikawọgbera mọ. A mọ pe awọn ọlọpaa, OPC ati Amọtẹkun n gbiyanju, ṣugbọn a gbọdọ kun wọn lọwọ lati fẹsẹ eto aabo rinlẹ nilẹ Yoruba. Idi niyi ti a fi ṣedasilẹ ẹṣọ alaabo tuntun kan to jẹ tiwa-n-tiwa, to maa ro eto aabo ilẹ Yoruba ni pataki, lagbara. Ẹ ku oju lọna, a maa too ṣiṣọ loju eegun ẹ laipẹ, ẹṣọ alaabo tuntun n bọ ni Guusu/Iwọ-Oorun ilẹ yii.”
Awọn ọrọ yii ni Aarẹ-ọna-kakanfo ilẹ wa, to tun jẹ olori ẹgbẹ Oodua Peoples Congress, OPC, Iba Gani Adams fi sin awọn olugbọ rẹ atawọn oniroyin ni gbẹnrẹ ipakọ nipa ikọ eleto aabo tuntun kan to ni wọn maa too ṣefilọlẹ rẹ nilẹ Yoruba laipẹ.
Nibi ipade pẹlu awọn oniroyin kan to waye l’ọjọ Abamẹta, Satide yii, l’Ekoo, lọrọ ọhun ti jade.
Gani Adams ni lajori iṣẹ ikọ alaabo yii ni lati fọwọ dain-dain mu eto aabo ilẹ Yoruba, ni pataki, ọrọ idaabo bo awọn agbẹ ati oko wọn kuro lọwọ awọn Fulani darandaran ti wọn n dunkooko mọ wọn.
O ni eto aabo yii maa lagbara gidi, tori o maa gbeja ko awọn ọbayejẹ Fulani darandaran, awọn ajinigbe, awọn adigunjale, ẹgbẹ okunkun, afipabanilopọ atawọn iwa mi-in to ti n fẹsẹ wa gbongbo nilẹ Yoruba.
Gani Adams ni gbogbo awọn tọrọ kan nipa igbese pataki yii maa pesẹ sibi apero kan to maa waye n’Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹta yii, o nibẹ lawọn ti maa fẹnu ọrọ jona nipa eto ọhun.
Gani Adams, Yinka Odumakin (agbẹnusọ ẹgbẹ Afẹnifẹre) ati agba ẹgbẹ ọhun kan, Ṣọla Lawal, ni wọn jọ bawọn oniroyin sọrọ lọjọ Abamẹta.
Awọn mẹtẹẹta lo tẹnumọ pataki iṣẹ agbẹ, wọn koro oju si bawọn Hausa kan ṣe lawọn o ni i ko ounjẹ wa silẹ Yoruba mọ, wọn si ni awọn agbaagba ilẹ Yoruba ko ni i laju silẹ ki eto aabo fun awọn agbẹ ti wọn n pese ounjẹ ti gbogbo wa n jẹ di yẹpẹrẹ.