Ṣẹgun ra ọkada lọwọ ẹni to pade lẹwọn, lo ba loun ko mọ pe ẹru ole ni

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta   

Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin kan, Ṣẹgun Ṣofẹla, to pe ara ẹ ni ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27) sọ pe ọrọ ọlọrọ toun ko mọ nipa ẹ lo gbe oun de ọgba ẹwọn lọdun to kọja, sibẹ, ohun ti ko jiyan ẹ ni pe oun ti ṣẹwọn ri.

Asiko to wa lẹwọn niluu Abẹokuta naa lo pade ẹlẹwọn bii tiẹ kan to ta ọkada fun un lẹyin ti wọn jọ jade lẹwọn ọhun.

Nibi ti Ṣẹgun ti n gun ọkada naa kiri ni Sango lawọn ọlọpaa ti mu un loṣu keji, ọdun yii.

Iṣẹ awọn to n tun ọkada ṣe ni Ṣẹgun sọ pe oun n ṣe, o si tun maa n gun ọkada pẹlu lati fi ṣiṣẹ.

Nigba to n ba ALAROYE sọrọ l’Eleweeran lọsẹ to kọja yii, o ni ọrẹ timọtimọ loun ati bọbọ to ta ọkada naa foun nigba tawọn wa lẹwọn, nigba tawọn si kuro lẹwọn, awọn ṣi n ṣe ọrẹ awọn lọ.

Ṣẹgun sọ pe ọjọ kan ni ọrẹ oun ẹlẹwọn naa de pẹlu ọkada kan to ni oun fẹẹ ta. O ni o ko iwe ọkada naa wa ti gbogbo ẹ pe perepere, ohun to jẹ koun gba lati ra a lọwọ ẹ niyẹn.

O fi kun un pe oun ti n gun ọkada naa kiri l’Abẹokuta ti ko si wahala, afi lọjọ kan toun lọ si Sango, ti awọn ọlọpaa da oun duro ti wọn si ni ọkada ti wọn ji gbe loun n wa kiri.

O ni awọn ọlọpaa sọ pe awọn ti n wa ọkada naa latigba ti ẹni to ni in ti fẹjọ sun pe wọn gbe ọkada oun lọ. Bi wọn ṣaa ṣe mu oun niyẹn ti wọn gbe oun pada si olu ileeṣẹ wọn ni Eleweeran, l’Abẹokuta.

Apa oriṣiiriṣii lo wa lara ọkunrin yii, nigba ti akọroyin wa beere pe bawo lo ṣe jẹ to fi gbogbo ara ṣe àpá bayii, Ṣẹgun sọ pe oun lasidẹnti ni. Nipa taaatu to ya sara nkọ, ko ri nnkan kan sọ.

Ọkunrin yii ṣi wa lahaamọ ọlọpaa, oun naa yoo de kootu biṣẹ ba ti bẹrẹ.

Leave a Reply