Baba Ijẹṣa maa pada sile-ẹjọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii

Faith Adebọla, Eko

Ọjọbọ, Tọsidee, to n bọ yii, ni gbajugbaju adẹrin-in poṣonu ilẹ wa nni, Ọlanrewaju James Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa yoo tun fara han niwaju adajọ, ṣugbọn lọtẹ yii, ile-ẹjọ to maa gbọ ẹsun rẹ ki i ṣe Yaba, kootu kan niluu Ikẹja ni wọn n wọ ọ lọ.

Ba a ṣe gbọ, ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun akanṣe, Special Offences Court, niwaju Onidaajọ Abilekọ Oluwatoyin Taiwo ni Baba Ijẹṣa yoo ti bẹrẹ igbẹjọ rẹ lakọtun lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa yii.

Lara awọn ẹsun tijọba ipinlẹ Eko to pe oṣere naa lẹjọ le lori ni fifọwọkan ọmọde lọna aitọ, biba ọmọde laṣepọ, igbiyanju lati ba ọmọde laṣepọ ati titẹ ẹtọ ọmọde loju.

Bakan naa ni agbẹjọro fun Baba Ijẹṣa, Ọgbẹni Kayọde Ọlabiran, ti kọwe ṣọwọ sile-ẹjọ yii lati beere pe ki wọn gbe ẹbẹ Baba Ijẹṣa fun beeli yẹwo, ki wọn si yọnda fun un ko le maa tile waa jẹjọ rẹ.

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, lo wa lori iwe ibeere fun beeli ọhun, wọn si ṣalaye sinu rẹ pe ipo ailera Baba Ijẹṣa ti n buru si i lahaamọ to wa, ati pe ko saaye fun un lati ri itọju to peye gba, eyi si lewu gidi fun iwalaaye rẹ.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu karun-un, ni adajọ Agba ipinlẹ Eko ti kọkọ fun ọkunrin naa ni beeli, ṣugbọn ko ṣee ṣe fun un lati ri awọn oniduuro ti won ni ko mu wa, eyi lo mu ko ṣi wa lahaamọ awọn agbofinro ni Panti, Yaba.

Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii, wọn gbe afurasi ọdaran naa lọ sile-ẹjọ Majisreeti to wa ni Yaba, o si fara han fun igba akọkọ, wọn ka awọn ẹsun ti wọn fi kan an si i leti, o si loun ko jẹbi.

Ṣugbọn igbẹjọ rẹ ko le tẹsiwaju nile-ẹjọ naa nigba ti agbefọba pe akiyesi adajọ si iwe ipẹjọ mi-in tijọba ipinlẹ Eko fi pe Baba Ijẹṣa lẹjọ si kootu to n gbọ ẹsun akanṣe n’Ikẹja yii.

Akiyesi yii lo mu ki adajọ Majisreeti yii paṣẹ ki wọn da afurasi ọdaran yii pada sahaamọ awọn ọlọpaa, o si yọwọ yọsẹ ninu ẹjọ naa.

Leave a Reply