Ẹgbẹ oṣelu PDP n lewaju pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹwaa

Florence Babaṣọla, Osogbo

Titi di aago mẹwaa alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ti wọn si n ka ibo ipinlẹ Ọṣun lọwọ, ẹgbẹ oṣelu PDP lo n lewaju pẹlu ibo ẹgbẹrun mẹwaa.

Ninu ibo bii ẹẹgbẹrun lọna ọgọjọ (150,000) ti wọn ti ka, Ademọla Adeleke ti ni ibo ẹgbẹrun mẹrinlelọgọrin ati diẹ, (84, 063), nigba ti Gomina Oyetọla ni ibo ẹgbẹrun mọkanlelaaadọrin (71, 830)

ati diẹ.

Ẹgbẹ oṣelu SDP ati Labour lo n tẹle wọn lẹyin, nitori ibo ti ẹnikọọkan wọn ni ko pe irinwo, o kan le diẹ ni ọọdunrun ni.

Bakan naa ni adari eto ipolongo ibo fun Gboyega Oyetọla, Sẹnetọ Ajibọla Basiru, koro oju si bi awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe n jijo jagini jodo pe awọn lawọn wọle. Wọn ni igbesẹ naa ko bojumu, nitori wọn ko ti i ka ibo tan, bẹẹ lawọn mi-in naa si n dibo lọwọ.

O fi kun un pe iru igbesẹ yii le da wahala silẹ l’Ọṣun.

Leave a Reply