Ọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogoji (44) kan, Emmanuel Udoh, to jẹ ọmọ bibi ijọba ibilẹ Ini, nipinlẹ Akwa Ibom, ti wọn ni o n ba ọmọ bibi inu ẹ lajọṣepọ ti sọ pe ohun ko ri ohun to buru ninu koun maa ba ọmọ oun lajọṣepọ.
Gẹgẹ bi Emmanuel Udoh ti wọn fi panpẹ ofin gbe lẹyin to ba ọmọ ẹ sun tan nile wọn to wa l’Ojule keji, Command Road, lagbegbe Meiran, nipinlẹ Eko, ṣe sọ, o lọmọ oun ko nilo ololufẹ kankan nigba toun wa nilẹ lati maa tẹ ẹ lọrun.