Aṣa wa ko di ẹsin wa lọwọ, ẹ jẹ ka ṣegbelarugẹ aṣa wa – Alao Adedayọ

Florence Babaṣọla

Oludasilẹ ati alakoso iwe iroyin ALAROYE, Alagba Alao Adedayọ ti ke si gbogbo ọmọ ilẹ kaaarọ-oo-jiire lati ṣa gbogbo ipa wọn lori awọn igbesẹ to le mu idagbasoke ba aṣa Yoruba.

Nibi ayẹyẹ ọsẹ oge to wa lati ṣagbelarugẹ lilo aṣọ adirẹ, eleyii ti ileeṣẹ aṣa atibudo isẹmbaye l’Ọṣun pẹlu ajọṣepọ Musty Great Development and Alexandria Jones Cultures, ni USA ṣagbekalẹ rẹ ni Alagba Alao ti woye pe ọwọ yẹpẹrẹ ti a fi n mu ọrọ aṣa Yoruba n ṣakoba pupọ fun iran yii.

Adedayọ ṣalaye pe “Aṣa wa ko di ẹsin wa lọwọ, bi a ba ṣe gbe aṣa wa larugẹ to naa ni yoo ṣe ran wa lọwọ to. Awọn aṣa kan wa to jẹ ti Yoruba, to jẹ pe kaakiri agbaye lawọn ti ki i ṣe Yoruba n fi i jẹun, ti wọn fi n mu idagbasoke ba ọrọ-aje wọn.

“Ko si ohun to ṣe awa ti a ni aṣa ti a ko fi le lo o lati mu idagbasoke ati itẹsiwaju ba ipinlẹ tabi orileede wa lapapọ. Awa ti a ki i ṣe ọmọ ipinlẹ Ọṣun maa n fi Ọṣun yangan nigba ti a ba lọ si ilẹ okeere nitori ohun ti ọpọ wọn ma a n beere ni pe bawo ni wọn ṣe n ṣe Ọṣun Oṣogbo.

“Ṣugbọn mo fẹẹ rọ ijọba pe ẹran ti a ba ta, ti a ko ba tọ ọ, ẹran idin ni. Iyẹn ni pe ti a ba ṣe agbekalẹ nnkan, ti a ko ba tẹ siwaju lori ẹ, anfaani to yẹ ka ri lori ẹ, a le ma ri i.

“Inu mi dun nigba ti kọmiṣanna n sọrọ lẹẹkan pe ohun pataki ti eto yii da le lori  ni igbelarugẹ ati sisọ di owo aṣọ adirẹ. Ile la ti i ko ẹṣọ lọ sode, ti a ba fẹ ki adirẹ ta, ki awọn oyinbo maa ra a, ẹ jẹ ka bẹrẹ lati ọdọ ara wa funra wa.

“Ko si ohun to ṣe oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọṣun ti wọn ko le wọ adirẹ lọ sibi iṣẹ, ko si ohun to ṣe awọn gbajugbaja Ọṣun ti wọn ko le wọ adirẹ lọ sibi okoowo wọn, ko si ohun to ṣe wa nipinlẹ yii ti a ba ni ṣiṣe ti ẹ fi n sare wa si Eko waa mu ankara ati leesi, ti a ko le ṣe igbelarugẹ adirẹ olowo pọọku ati olowo nla.”

Ninu ọrọ ti kọmiṣanna fun ọrọ aṣa atibudo isẹmbaye l’Ọṣun, Dokita Ọbawale Adebisi, o ni afojusun Gomina Oyetọla ni lati ṣamulo gbogbo awọn ibudo to ni i ṣe pẹlu aṣa ilẹ Yoruba.

Ọbawale ṣalaye pe oriṣiiriṣii awọn ibudo to le jẹ orisun ipawowọle labẹnu funjọba lo wa kaakiri ipinlẹ Ọṣun, ijọba si ti ṣetan lati ṣiṣẹ papọ pẹlu ẹnikẹni ti yoo mu erongba ijọba wa simuṣẹ lori wọn.

O fi kun ọrọ rẹ pe adirẹ ṣiṣe yoo di eyi tijọba yoo mojuto nipinlẹ Ọṣun bayii lati le ṣeranwọ fun owo ti yoo maa wọle labẹnu funjọba latibẹ.

Leave a Reply