A ko ni i faaye gba iwa janduku ati iyanjẹ latọwọ ẹgbẹ oṣelu APC Ọṣun mọ – PDP

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) nipinlẹ Ọṣun ti ke si ajọ agbaye lati tete kilọ fun ẹgbẹ oṣelu APC ati oludije wọn nipinlẹ Ọṣun, Gomina Gboyega Oyetọla, lati dẹkun ṣiṣe ikọlu si awọn ọmọ ẹgbẹ naa.

Nibi ipade oniroyin kan ti ẹgbẹ naa pe niluu Oṣogbo lọjọ Wẹsidee ni adele-alaga wọn, Dokita Akindele Akintunde, sọ pe ikanra ni ọrọ ba de fun ẹgbẹ oṣelu APC bayii nigba ti wọn ri i pe awọn araalu ti kuro lẹyin wọn patapata.

Akintunde ṣalaye pe bi awọn tọọgi ẹgbẹ APC ṣe kọ lu awọn ọmọ ẹgbẹ PDP lasiko ti wọn n lọ si aafin Ataọja tiluu Oṣogbo, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, jẹ iwa ti ko bojumu rara, ti ko si yẹ keeyan ba lọwọ ọmọluabi.

O fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo igbiyanju ẹgbẹ naa lati lo awọn aaye to fẹ daadaa niluu Oṣogbo fun aṣekagba ipolongo wọn ti yoo waye lọsẹ to n bọ lo ja si pabo pẹlu bijọba ko ṣe ti i gba pe kawọn lo Freedom Park, tabi Stadium.

O waa ke si ẹgbẹ APC ati oludije rẹ, Oyetọla, lati tete gba kamu, ki wọn mọ pe awọn araalu ti pinnu lati tẹle Sẹnetọ Ademọla Adeleke to jẹ oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP.

Bakan naa ni ọkan lara awọn agbaagba ẹgbẹ PDP, Wale Ọladipọ, sọ pe o ṣi n ṣe ẹgbẹ oṣelu APC bii ala pẹlu bi awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ṣe tẹwọ gba Sẹnetọ Ademọla Adeleke, idi niyẹn ti wọn si fi n japoro kaakiri.

Oladipọ ni ẹgbẹ PDP ko ni i faaye gba iwa janduku ti ẹgbẹ APC n hu si wọn mọ, bẹẹ ni awọn ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu bi wọn ṣe n huwa ti ko tọ si awọn ori-ade ati ọrun ilẹkẹ nipinlẹ Ọṣun.

O ni Oyetọla ati awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ti pa awọn araalu ti latọjọ pipẹ, awọn oṣiṣẹ ijọba n jiya, awọn oṣiṣẹ-fẹyinti n ku nigba ti wọn ko rowo tọju ara wọn, idi niyẹn ti wọn fi n fẹ ayipada ti yoo wa latọwọ ẹgbẹ PDP.

O waa ranṣẹ ikilọ sijọba to wa lode bayii pe ilu Oṣogbo gan-an lawọn yoo ti ṣe aṣekagba ipolongo idibo awọn lọsẹ to n bọ, ko si gbọdọ si ikọlu kankan.

Leave a Reply