Ẹlẹwọn bii ẹgbẹta lo sa lọ ni Kuje, Abba Kyari atawọn ọdaran nla kan dawati

Faith Adebọla

 Ko ti i daju boya awọn afẹmisofo Boko Haram, tabi ISWAP ni wọn, abi awọn agbebọn ti wọn n jiiyan gbe kaakiri Oke-Ọya ni wọn, ṣugbọn niṣe lawọn agbebọn rẹpẹtẹ kan ti wọn dihamọra wamuwamu pẹlu aṣọ dudu boju, wọn ya bo ọgba ẹwọn nla ti Kuje, l’Abuja, ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ karun-un, oṣu Keje, ọdun yii, wọ fi bọmbu fọ fẹnsi ati ogiri ẹwọn naa, wọn tu ọpọ awọn ẹlẹwọn silẹ, wọn si ko awọn kan lara wọn lọ.

Ba a ṣe gbọ, ọkọ akẹru bii mẹwaa lawọn agbebọn naa gbe wa, wọn tu awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram ti wọn wa lahaamọ ẹwọn naa silẹ, wọn ko wọn lọ. Lẹyin ti wọn ti lọ tan, wọn lawọn ẹlẹwọn yooku fẹsẹ fẹ ẹ, ko si sawọn ẹṣọ alaabo to di wọn lọwọ, awọn ẹṣọ to n ṣọ ọgba ẹwọn naa ti sa lọ lasiko akọlu ọhun.

Nigba ti eruku akọlu naa yoo fi rọlẹ, awọn ẹlẹwọn to ṣẹku ko to ọgbọn, bẹẹ eeyan to ju ẹgbẹrun kan lọ lo wa lahaamọ ọgba ẹwọn naa ki iṣẹlẹ naa to waye.

Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn naa tiṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ sọ pe ọna ẹyin lawọn agbebọn naa gba wọle, lẹyin ti wọn ti fọ ogiri ẹwọn tan ni awọn ẹlẹgbẹ wọn yooku wa bọọsi akẹru wọle, ti wọn si ko awọn ẹlẹwọn sa lọ. Lẹyin naa ni wọn tun dana sun awọn ọkọ ijọba ati aladaani to wa lagbegbe ẹwọn naa.

Tẹ o ba gbagbe, ọgba ẹwọn yii ni ọpọ lara awọn eeyan nla nla tijọba n ba ṣẹjọ lọwọ tabi ti wọn ti gba idajọ wọn ti n ṣẹwọn. Lara wọn ni gbajugbaju Igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa tẹlẹ ri ati olori ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n ba ṣẹjọ pe o lọwọ ninu okoowo egboogi oloro, o si tun ni ajọṣe pẹlu afurasi onijibiti Hushpuppi, DCP Abba Kyari, ati awọn ẹmẹwa rẹ.

Ọpọ awuyewuye lo ti dide nipa ibi ti ọkunrin naa wa bayii, awọn kan n sọ pe awọn ẹṣọ alaabo ti gbe e lọ sahaamọ mi-in, awọn kan si n sọ pe ọkunrin naa ti sa lọ.

Oṣiṣẹ kan ti ko fẹ lati darukọ ara ẹ sọ pe “a o ti i foju kan an, tori ko wa si adura owurọ Subhi laaarọ yii, gẹgẹ bo ṣe maa n ṣe, ṣugbọn mi o mọ ohun to n ṣẹlẹ.”

Minisita fun eto aabo nile wa nipasẹ akọwe agba ileeṣẹ to n mojuto ọrọ abẹle nilẹ wa, Dokita Shuaibu Belgore, ti fẹnu ara rẹ ṣalaye fawọn oniroyin pe bii ẹgbẹta (600) awọn ẹlẹwọn ni wọn ti sa kuro ninu ọgba ẹwọn naa.

Ọkunrin naa ṣalaye yii lasiko to ṣabẹwo lọ sinu ọgba ẹwọn naa lati wo bi nnkan ṣe bajẹ si. Nibẹ lo ti sọ pe ninu bii ẹgbẹrun kan o din mẹfa (994), awọn ẹlẹwọn to wa ninu ọgba naa, bii igba mẹta (600), lo ti raaye sa jade ninu wọn.

Bẹẹ lo ni ọkan ninu awọn oṣiṣẹ aabo ara ẹni laabo ilu, (civil defence) ba iṣẹlẹ naa lọ lasiko ti awọn afẹmiṣofo naa kọju ija sawọn to n ṣọ ọgba ẹwọn ọhun.

Titi di ba a ṣe n sọ yii ni ko ti i sẹni to mọ ibi ti Abbah Kyari, gomina ipinlẹ Taraba tẹle, Jolly Nyame, ati ti ipinlẹ Plateau tẹlẹ, Joshua Dariye, atawọn eeyan nla nla mi-n to wa ninu ọgba ẹwọn naa wa.

Leave a Reply