Eeyan meji ku nibi ijamba ọkọ oju omi l’Ekoo

Monisọla Saka

Obinrin meji lo ti dero ọrun ninu ijamba ọkọ oju omi to ko ero bii ogun to dojude ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ ku iṣẹju mẹẹẹdogun l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nibudokọ oju omi Ipakodo, lagbegbe Ikorodu, lọ si Eko Idumọta (Lagos Island).

Ninu atẹjade kan ti Alakooso agba fun ileeṣẹ eto irinna oju omi ipinlẹ Eko (LASWA), Oluwadamilọla Emmanuel, buwọ lu l’Ọjọruu, Wẹsidee, eeyan mẹẹẹdogun ni wọn ri doola ninu awọn ero to wa ninu ọkọ oju omi naa.

Gẹgẹ bi atẹjade ti wọn gbe jade ọhun, “Ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ ku iṣẹju mẹẹẹdogun lonii, Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Keje, ọdun 2022, ọkọ oju omi elero ogun kan to ko ero mẹtadinlogun ti wọn n pe ni “R & N 2” dojude lojiji ni ko pẹ pupọ to gbera ni ibudokọ Ipakodo, lagbegbe Ikorodu, lasiko to n ko ero lọ si ibudokọ oju omi Eko Idumọta.

“Awọn ẹṣọ alaabo to n ri si eto irinna ori omi atawọn ẹṣọ to maa n gbe awọn eeyan jade ninu omi lasiko iṣẹlẹ pajawiri ti wọn jẹ ẹka (LASWA), ni wọn sare lọ si agbegbe iṣẹlẹ naa, ti wọn si ri eeyan mẹẹẹdogun gbe jade laaye.

“Awọn obinrin meji kan ti wọn o laju, ti wọn o si mira, ni wọn sare gbe digbadigba lọ sile-iwosan to wa nitosi ibẹ fun itọju. Ṣugbọn loju-ẹsẹ ni awọn dokita ti sọ pe awọn eniyan ti wọn gbe wa ti jẹ Ọlọrun nipe.

“Awakọ oju omi ohun wa l’agọọ awọn ajọ eleto aabo tọrọ kan fun ifọrọwanilẹnuwo. Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, iwadii ṣi n lọ lọwọ lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.”

Leave a Reply