Ọba ilu ṣegbeyawo pẹlu alegba, ni wọn ba fẹnu kora wọn lẹnu

Kayeefi nla ni ọrọ ọba ilu kan ti wọn n pe ni San Pedro Huwmelula, Victor Hugo Sosa, gbe alegba niyawo, to si tun wọ aṣọ leesi funfun olowo nla, iru eyi tawọn iyawo maa n wọ gẹgẹ bii aṣọ igbeyawo fun un, ni abule kan lorileede Mexico. Ọkọ naa ko si aṣọ olowo iyebiye, toun ti tai to so mọ ọrun si i. Awọn eeyan si wa nibẹ ti wọn waa ba a ṣajọyọ igbeyawo to ṣe pẹlu ‘ololufẹ’ rẹ yii.

Ọba ọhun tun ṣe paripari ẹ nigba to fẹnu ko iyawo ẹ tuntun yii lẹnu.

Ẹranko afayafa yii ni wọn nigbagbọ pe o duro fun ilẹ, idapọ oun ati olori ilu yii duro fun isopọ eeyan ati oriṣa. Gẹgẹ bii igbagbọ, aṣa ati iṣe ilu naa, ọpọlọpọ ire ni ajọṣepọ eeyan ati ẹni mimọ yii yoo mu wọ ilu wa.

Alegba ti ọjọ ori rẹ to ọdun meje yii ni wọn n pe ni ‘Little Princess’ (ọmọọba obinrin kekere.) Lasiko ti ayẹyẹ igbeyawo n lọ lọwọ, niṣe ni wọn fi nnkan de ẹnu ẹ nitori ko ma baa lọọ fo mọ eeyan lojiji, ko si tibẹ lanu ge eeyan jẹ.

Nigba to n sọrọ, Ọba Sosa ni, “A n beere fun ọpọ ojo, ounjẹ lọpọ yanturu ati ọpọlọpọ ẹja ninu awọn odo wa”.

Alarinrin gbaa ni ayẹyẹ igbeyawo ọhun gẹgẹ bi awọn eniyan ilu, awọn alejo pataki atawọn alabaaṣe ṣe fi ijokoo yẹ wọn si, bi wọn ṣe n jo, bẹẹ ni wọn n yọ ṣẹṣẹ ninu fidio ti wọn sọ sori afẹfẹ ọhun. Awọn mi-in ninu wọn tun n sọ fun ọba ko tubọ fẹnu ko ‘iyawo ọṣingin’ ẹ lẹnu si i. Tayọtayọ ni wọn si n wo ọkọ iyawo bo ṣe n ba iyawo ẹ jo fun igba akọkọ.

Ọpọlọpọ awọn eeyan ni ọrọ yii n ṣe ni kayeefi, onikaluku si n sọ ero ẹ lori ẹrọ ayelujara. Bawọn kan ṣe n sọ pe aṣakaṣa gbaa ni, bẹẹ lawọn mi-in ni ṣe obinrin naa ni ko waa si laye mọ to fi jẹ pe ẹranko lo tun kan. Awọn kan tilẹ sọ pe bi wahala ṣe maa n bẹrẹ ree, nitori afọwọfa ni nnkan ti ọkunrin naa ṣe, agbara rẹ ko si ni i ka a nigba ti ẹranko ba yari.

Ọrọ apanilẹrin-in lawọn kan tilẹ sọ, wọn ni bawo ni wọn ṣe fẹẹ maa ṣe ohun ti lọkọ-laya maa n ṣe, abi iyawo palọ lasan ni.

Leave a Reply