Aadọta miliọnu lawọn agbebọn to jiiyan mẹjọ gbe n’Itapaji-Ekiti n bere fun

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Lẹyin ọsẹ kan ti awọn agbebọn ji awọn mẹrin kan gbe ni Ayebode-Ekiti, awọn ajinigbe ti tun ji awọn mẹjọ miiran gbe ni Itapaji-Ekiti, nijọba ibilẹ Ikọle, ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Awọn eeyan naa si ti kan si mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe ọhun pe aadọta miliọnu lawọn maa gba kawọn too le tu wọn silẹ.

Ẹnikan tọrọ naa ṣoju rẹ ṣalaye fawọn oniroyin niluu Ado-Ekiti pe ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ni awọn ajinigbe naa ya bo ilu yii, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn soke leralera. Fun bii wakati meji ni wọn ni iro ibọn naa fi n dun. Niṣe ni ibẹruboju gba ọkan awọn araalu, ti onikaluku si n sa kijokijo kiri. Lasiko ikọlu yii ni wọn ji awọn mẹjọ kan ti wọn wa fun eto isinku kan niluu naa.

ALAROYE gbọ pe ọkunrin ẹni aadọta ọdun kan to jẹ babalawo ni wọn n ṣe oku rẹ. Eyi mu ki awọn eeyan lati awọn ilu mi-in wa sibi isinku naa. Lara awọn ti wọn wa ọhun ni wọn ti ko eeyan mẹjọ lọ.

Ọkada ni awọn ajinigbe ti wọn to bii meje yii gbe wọn ilu naa gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ti wọn si dihamọra bii ẹni to n lọ soju ogun pẹlu oriṣiiriṣii ohun ija oloro bii ibọn, ada atawọn ohun ija mi-in.

Bi awọn to wa ninu ile naa ṣe n gburoo ibọn ti wọn n sa jade, ọwọ awọn ajinigbe ọhun ni wọn n bọ si, ti wọn si n ko wọn wọnu igbo lọ.

Mẹrinla lawọn eeyan naa, ṣugbọn mẹfa ninu wọn raaye sa mọ awọn ajinigbe naa lọwọ.

O ṣalaye pe ni kutukutu aarọ ọjọ Wẹsidee ni ọkan ninu awọn ajinigbe yii pe lara awọn mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe, ti wọn si beere fun aadọta miliọnu naira ki wọn too le ri awọn eeyan wọn gba.

Wọn ni aisi agọ ọlọpaa ni agbegbe Itapaji, Ayebode, Oke-Ako ati Irele-Ekiti lo fa a ti awọn ajinigbe fi n ṣe ikọlu sawọn ilu naa lemọlemọ, nitori Ikọle-Ekiti to to ọgọrun-un kilomita si ilu Itapaji ni agọ ọlọpaa to sun mọ agbegbe naa wa.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe awọn ọlọpaa ti wa ni gbogbo inu igbo to wa ni agbegbe naa, titi lọọ jade si ipinlẹ Kwara.

O ṣeleri awọn agbofinro yoo sa gbogbo ipa wọn lati gba awọn ti wọn ji gbe naa jade lai jẹ pe wọn san owo itanran ti wọn n beere fun.

Leave a Reply