Ogo eto ẹkọ ti sọnu lasiko ijọba to kogba wọle ni Kwara – Gomina Abdulrazak 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gomina ipinlẹ Kwara Abdulrahman Abdulrasaq, ti sọ pe ojusun iṣejọba oun ni lati da gbogbo wara ati oyin to ti lọ nipinlẹ Kwara pada, paapaa ju lọ lẹka eto ẹkọ, to si ni ọrọ ti Saraki sọ pe aṣiṣe ni Kwara ṣe bi wọn ṣe fibo le e danu lọdun 2019, aṣọ gbọnnu lasan ni, tori pe ipinlẹ Kwara o gbọdọ tun pada si ẹsẹ aarọ mọ, nibi ti wọn ti n pin iṣẹ olukọ fawọn eeyan Saraki nipade oloṣelu lawọn wọọdu gbogbo.

Ọjọru, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni Gomina Abdulrazak sọrọ yii nibi ifilọlẹ ṣiṣe idanilẹkọọ fawọn olukọ tuntun (TESCOM) ti wọn ṣẹṣẹ gba ṣiṣẹ olukọ nipinlẹ naa. Gomina tẹsiwaju pe ogo eto ẹkọ ti sọnu, o si ti dẹnukọlẹ bii ọkọ ti ko dara mọ lasiko iṣejọba awọn Saraki, ati pe o ti ni loju jọjọ ki wọn maa pin iṣẹ olukọ laarin awọn oloṣelu ẹgbẹ wọn, ti wọn o si ni i gba awọn olukọ to kunju oṣunwọn. Gomina ni oun le fọwọ sọya pe awọn olukọ to dantọ ni awọn gba ṣiṣẹ bayii, tawọn si n ṣe idanilẹkọọ fun wọn tori pe ojusun iṣejọba oun ni lati ri i pe ogo to ti lọ lẹka eto ẹkọ pada sipo fun ọjọ ọla rere awọn ogo wẹẹrẹ.

Abdulrasaq gboriyin fawọn alaṣẹ ileeṣẹ to n mojuto eto ẹkọ fun bi wọn ṣe ṣeto idanilẹkọọ naa fawọn olukọ tuntun, bakan naa lo rọ awọn olukọ tuntun ọhun pe ki wọn jẹ ẹni ti yoo ṣee mu yangan lawujọ, ki gbogbo ilakaka ijọba lori ọrọ eto ẹkọ to ye kooro fawọn ogo wẹẹrẹ le yọ. O fi kun un pe ijọba yoo sa gbogbo ipa rẹ lati mu aye gbẹdẹmukẹ fawọn olukọ, paapaa ju lọ lori ọrọ igbega ati nnkan miiran to fara pẹ ẹ. Gomina ni ti a ba fẹẹ sọ itan Aarin Gbungbun Ariwa orile-ede yii, ta a ba ti i sọrọ ipinlẹ Kwara, itan naa ko ti i kun to, idi niyi ti wọn fi gbọdọ fi apẹẹrẹ rere lelẹ lẹka eto ẹkọ, ti yoo si wa ninu iwe itan titi aye ainipẹkun.

 

 

Leave a Reply