Aarẹ Buhari ti ṣẹri pada o, o loun ko lọ siluu oyinbo fun ayẹwo mọ

Aarẹ Buhari ti tun so irinajo to fẹẹ lọ niluu oyinbo, nibi to ti fẹẹ lọ gba itọju rọ, o ti sọ ọ di ọjọ mi-in ọjọọre.

Oludamọran Aarẹ lori eto iroyin, Fẹmi Adeṣina, lo fi eleyii lede lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, pe Aarẹ Buhari ko lọ siluu oyinbo lati lọọ ri awọn dokita rẹ mọ gegẹ bi awọn ṣe kede tẹlẹ. O ni o ti sun un siwaju di ọjọ mi-in, ọjọọre.

O ni awọn yoo maa kede ọjọ irnajo naa to ba ti tun ya.

Leave a Reply