Adajọ ti ni ki wọn yẹgi fun mẹkaniiki to digunjale n’Ileṣa

Idowu Akinrẹmi, Ikire

 Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni Adajọ Isiaka Adeleke, ti ile-ẹjọ giga ilu Ileṣa, dajọ iku fun ọkunrin mẹkaniiki kan, Ṣọla Emorua, ẹni ti wọn lo jẹbi ẹsun idigunjale ati igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi.

Ọdun 2018 ni igbẹjọ Ṣọla bẹrẹ ni kootu naa, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun naa, ni wọn kọkọ gbe e wa sile-ẹjọ ọhun, ti wọn fẹsun idigunjale ati igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi kan an, k’adajọ too ni ki wọn lọọ yẹgi fun un lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kejila, ọdun 2020.

Nigba to n ṣalaye ẹjọ naa fun kootu, Aṣoju ileeṣẹ eto idajọ, Mọtọlani  Ṣokẹfun, sọ pe ni nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ ọjọ keje, oṣu karun-un, ọdun 2015, ni olujẹjọ atawọn yooku rẹ duro pẹlu awọn nnkan ija bii ibọn, ada ati ọbẹ lọwọ wọn, lagbegbe Ayorunbọ, loju ọna Ileṣa si Akurẹ, nipinle Ọṣun.

O ṣalaye pe wọn pawọ pọ ja awakọ tirela epo kẹrosinni kan torukọ rẹ n jẹ Ismaila Azeez lole, wọn si de e mọlẹ sinu igbo.

Ọsẹ diẹ lẹyin igba naa lo ni Emorua atawọn yooku ẹ tun digun ja awakọ epo bẹntiroolu mi-in torukọ tiẹ n jẹ Ibrahim Azeez lole, ọwọ ọlọpaa si tẹ meji ninu wọn nigba naa.

Ṣokẹfun ṣalaye pe awọn ọlọpaa ranṣẹ pe awọn awakọ tirela mejeeji yii fun iwadii, awọn mejeeji si jẹrii si i pe Emorua wa lara awọn adigunjale to kọlu awọn lọjọ tiṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Adajọ Adeleke sọ pe Ṣọla Emorua jẹbi ẹsun mejeeji ti wọn fi kan an, o si paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun un titi ti ẹmi yoo fi bọ lara ẹ.

Leave a Reply