Akẹkọọ to ni arun Korona kọ idanwo nibudo iyasọta ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣeto bi akẹkọọ-binrin ẹni ọdun mẹrindinlogun kan to ni arun Korona yoo ṣe maa kọ idanwo aṣekagba, WAEC, to bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nibudo iyasọtọ to ti n gbatọju.

Akọwe iroyin gomina to tun jẹ alukoro igbimọ amuṣẹya to n mojuto ọrọ Covid-19, Rafiu Ajakaye, lo kede ọrọ naa ninu atẹjade kan l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Akẹkọọ ọhun ti wọn forukọ bo laṣiiri lo jokoo kọ idanwo ẹkọ nipa Ọgbin (Agricultural Science), labẹ idari oṣiṣẹ ajọ to n ṣedanwo naa.

Adari ikọ to n gbogun ti arun Korona ni Kwara, Dokita Kudirat Ọladeji-Lambẹ ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe akẹkọọ naa ni arun ọhun lara, sibẹ, o ṣi le ṣe idanwo naa lai si idiwọ kankan.

O ni ọsẹ meji ni yoo lo nibudo naa tawọn yoo fi yẹ ẹ wo daadaa lati ri i pe kinni ọhun ko gbodi lara rẹ.

Lambẹ ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni awọn gbe e wa sibudo iyasọtọ naa. O ni ko lanfaani lati kọ idanwo ọjọ naa, ṣugbọn awọn ti ba ajọ WAEC sọ ọ bi wọn ṣe maa ṣe e.

 

Leave a Reply