Akwa Ibom lawọn ọmọbinrin keekeeke yii waa ṣiṣẹ aṣẹwo l’Ogun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ko din ni mejilelogun (22) awọn ọmọdebinrin ti awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ri ko lotẹẹli Kolab, n’Itele-Ọta, lọjọ keje, oṣu karun-un yii, ti i ṣe ọjọ Ẹti. Iṣẹ aṣẹwo ni wọn n ṣe nibẹ, ipinlẹ Akwa Ibom, ni Uyo, ni wọn ti waa n ṣaṣẹwo l’Ogun.

Olobo lo ta awọn ọlọpaa ti ACP Muhideen Obe, Eeria Kọmanda Ọta, fi ko awọn ikọ rẹ lọ si otẹẹli naa.

Nigba ti wọn debẹ, awọn ọmọbinrin tọjọ ori wọn bẹrẹ lati mẹwaa si mẹrinla ni wọn ba nibẹ rẹpẹtẹ ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ tawọn ọlọpaa naa debẹ.

Nigba ti wọn fọrọ wa wọn lẹnu wo, awọn ọmọde oloṣo naa ṣalaye pe wọn fi ọrọ didun tan awọn lati awọn abule awọn ni Akwa Ibom ni.

Wọn ni awọn to mu awọn wa sipinlẹ Ogun sọ pe iṣẹ lawọn fẹẹ waa ṣe nibi, awọn iṣẹ bii abanitaja nile itaja igbalode (Supermarkets) ati nile faaji (restaurants) ni wọn ni awọn n bọ waa ṣe nipinlẹ Ogun. Afi bawọn ṣe balẹ tan to jẹ otẹẹli lawọn ba ara awọn fun iṣẹ aṣẹwo.

Wọn fi kun alaye wọn pe ko si foonu lọwọ awọn mọ, awọn to ko awọn wa ti gba a, eyi ko jẹ ko ṣee ṣe lati pe awọn eeyan awọn labule pe iṣẹ aṣẹwo ni wọn n fi awọn ṣe bayii o.

Ṣa, wọn ti mu maneja otẹẹli naa, ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Isaac Ogbaji, ẹni ọdun mẹtelelọgbọn.

Bakan naa ni CP Edward Ajogun ti paṣẹ pe ki ẹka to n ri si ọrọ mọlẹbi ni Kọmandi Ọta maa ba ẹjo naa lọ. O ni ki wọn wa awọn to ko awọn ọmọde naa ri, ki wọn si mu wọn ṣikun lati jiya labẹ ofin.

 

Leave a Reply