Amọtẹkun ipinlẹ Ogun ti mu Taiwo to ṣa Rasaki pa nitori kòkó n’Ijẹbu-Igbo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

  Ọwọ ikọ Amọtẹkun ipinlẹ Ogun ti tẹ ọmọkunrin kan, Taiwo Fatai; ẹni ọdun mọkanlelogun, ti wọn lo ṣa agbẹ kan torukọ ẹ n jẹ Rasaki Aro pa sinu oko l’Oke-Ṣopẹn, Ijẹbu-Igbo.

Ninu atẹjade ti Olori Amọtẹkun nipinlẹ Ogun, Kọmandanti David Akinrẹmi, fi ṣọwọ si ALAROYE, o ni ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kọkanla yii, ni ọwọ ba Taiwo.

O fi kun un pe ọmọkunrin kan tun kun Taiwo lọwọ lati pa Rasaki, orukọ tiẹ ni Muyideen Adeọṣun. Olori Ogun fi kun un pe Muyideen sa lọ ni tiẹ, ọwọ ikọ Amọtẹkun ko tete ba a, ṣugbọn awọn ti pada ri oun naa mu, awọn si ti fa awọn mejeeji le ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lọwọ.

Atẹjade naa ṣalaye pe Taiwo ati Muyideen lọ soko Rasaki lati ji koko rẹ ni, awọn ko mọ pe oloko wa nibẹ.

Nibi ti wọn ti n ji koko ka ni Rasaki ti ri wọn, to si beere pe nibo ni wọn ti wa ti wọn waa n ja oun lole, ṣugbọn kaka kawọn ole naa sa, wọn ko sa, niṣe ni wọn bẹrẹ si i fiya jẹ Rasaki, ti wọn si bẹrẹ si i ṣa a ladaa titi ti wọn fi ṣa a pa sinu oko naa.

Nigba ti aṣiri wọn yoo tu ṣa, ọwọ ba Taiwo lẹyin iṣẹ ibi naa, Muyideen sa lọ, ṣugbọn ko pẹ pupọ ti ọwọ fi ba oun naa. Awọn mejeeji naa ni wọn jẹwọ pe awọn lawọn ṣa Rasaki pa, awọn Amọtẹkun to mu wọn si ko wọn fọlọpaa.

Leave a Reply