Aunti Sikira jẹwọ fun mi, o ni loootọ lọkunrin yẹn boun ṣe aṣemaṣe

Eke niyaale mi, Iya Dele. Eke gidi ni. Abi bawo lo ṣe mọ pe panti ti wọn mu wa sile wa, panti Aunti Sikira ni. Inu ile ni kaluku n sa panti ẹ si nigba taye ti daye ka maa ji ara ẹni ni pata kiri yii, ko sẹni to n sa pata ẹ sita ninu wa, emi o tiẹ ṣe e ri. Bi Iya Dele ṣe waa mọ pe panti toun ri lọwọ ẹni to waa fi ẹjọ sun Alaaji, panti Aunti Sikiria ni, iyẹn lemi tubọ fẹ ko ṣalaye. Ṣugbọn Safu to wa nibi to ti n sọ ohun to ṣẹlẹ fun wa ko le jẹ ki n maa lọ ọ nifun. Bo ba jẹ emi ati ẹ ni, mo mọ bi mo ṣe n mu un. Ṣebi Iyaale mi ni, Aunti Alakẹ Lakonko, mo mọ bi mo ṣe n mu un.

Ṣugbọn iyẹn gan-an tiẹ kọ lọrọ to wa nilẹ yii. Ohun to wa nilẹ ti le ju bẹẹ lọ. Ọrọ to ba ti di ti famili Alaaji, o ni bi mo ṣe maa n da si i, nitori mi o ki i fẹ wahala gbogbo wọn. Mo mọ wọn daadaa. Aunti Sikira lo si ti duro to n bẹ mi yii, latigba to ti gbọ pe awọn eeyan yii n bọ lo ti n waa bẹ mi, to n pe ki n gba oun, yeye ọmọ ni i gb’ọmọ, irukẹrẹ ni i gb’ọmọ Ọrunmila. Emi o kuku mọ ibi to ti n gbọ awọn ohun Ifa to maa n ju lulẹ nigba mi-in, boya owe lasan si ni, abi ki lo kan ọmọ Ọrunmila ninu gbogbo ohun to wa nilẹ yii.

Kinni kan ti mo laiki lọrọ ẹ, iyẹn Aunti Sikira naa ni pe bi ọrọ ba ti da bayii, yoo jẹwọ ni gbangba ni, ko si bi kinni naa ti le le to, yoo sọ pe loootọ ni, bi wọn yoo ba pa oun ki wọn kuku pa oun. Ko ju bẹẹ lọ. Ko si lojuti kan bayii, eyi ti n ko fẹ ninu ọrọ ẹ niyẹn. Bi eeyan ko ba ti lojuti, ko si ohun ti ko le ṣe. Aunti Sikira ko lojuti, ohun to si ṣe n ṣe bo ti n ṣe n kiri naa ree. Ṣugbọn emi ni kinni kan, iyẹn naa si ni pe aanu eeyan ki i pẹẹ ṣe emi, emi ki i fẹ ki aye da yẹyẹ eeyan silẹ, paapaa ẹni to ba ti mọ pe ohun toun ṣe ko dara, to si mura lati ṣe atunṣe. Bi ọrọ yẹn ṣe ri niyẹn.

Ko pẹ ti Iya Dele kuro ni ṣọọbu ti Aunti Sikira funra ẹ fi de, bo ti ri mi lo sare wọle, nigba ti mo si ni ko jokoo, bo ṣe n jokoo bayii, o bu sigbe ni. ‘Iyaa wa, temi ti bajẹ o! O ti bajẹ gan-an! Ti ẹ o ba ran mi lọwọ lasiko yii, aye mi maa bajẹ patapata ni! Bobinrin yẹn ma ṣe n wi niyẹn. Emi o si fẹẹ bẹ ṣaaju, n ko fẹẹ sọ fun un pe Iya Dele ṣẹṣẹ lọ ni, mo fẹ ko fi ẹnu ẹ sọ ohun to ṣẹlẹ, nitori bo ba mọ pe Iya Dele ti waa ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ni ṣọọbu, ko ni i fẹ bẹẹ rara, iyẹn si tun le dija tuntun. Nitori ẹ ni n ko ṣe sọ fun un, oju lagba i ya, agba ki i yanu.

Funra ẹ lo si tẹnu bọrọ, o ni obinrin oloriburuku kan lo waa ba oun nile to n pariwo pe ọkọ oun n ba oun sun, to si mu panti kan dani to waa fi han Alaaji pe panti toun ni. Ohun ti mo kọkọ beere ni pe ta lo ni panti, lo ba n wolẹ. Mo waa ni, Aunti Sikira, lo ba gboju soke lo wo mi, mo ni ṣe loootọ lọkọ obinrin naa ba ẹyin naa sun. Lo ba ni loootọ ni, ṣugbọn ẹẹkan naa ni, pe ọjọ to ba oun sun yẹn naa ni iyawo ẹ ka awọn mọ, nitori ọkunrin naa loun o le gba otẹẹli, ati pe iyawo oun ti lọ si Ibadan, o maa pẹẹ de, afi bawọn ṣe wa lori moṣan ti iyawo ẹ de.

Ninu gbogbo ọrọ yii, eyi to pa mi lẹrin-in ju niyẹn: Aunti Sikira funra ẹ lo fẹnu ara ẹ sọ pe nigba ti awọn wa lori moṣan lobinrin yẹn de, ori moṣan yẹn lo si n pa mi lẹrin-in nibẹ. Inu bi mi nigbẹyin ṣa, nitori mo beere ohun to fa a, mo ni ki lo n wa kiri, ki lo kuku de ti oun obinrin agbalagba bẹẹ maa maa ṣe iṣekuṣe. O ni oun ti mọ ọkunrin yẹn tipẹ, pe ki i ṣe pe awọn ṣẹṣẹ mọra, maanu-furẹndi toun n tẹle koun too pada si ọdọ Alaaji ni. Mo ni bo ba jẹ bẹẹ, ko yẹ ko tun sun mọ ọn mọ, gbogbo ohun to ṣe nigba ti ko ti i lọkọ, iyẹn ti lọ niyẹn, asiko to ti lọkọ, ko tun gbọdọ ya sibẹ yẹn mọ.

Lo ba ni misiteeki ni, oun ko ni i ṣe bẹẹ mọ, ki n ṣaa jẹ ki wọn dariji oun, ki wọn fi eleyii fa oun leti, oun o tun jẹ ṣe bẹẹ mọ. Lo ba bu sigbe, o n ke. Ẹkun to n sun yẹn lo jẹ ki aanu ẹ ṣe mi, nitori bi mo ṣe n wo o to n sunkun yii, niṣe lo darugbo wa loju mi, gbogbo faari ati akọ to maa n ṣe ko si nibẹ mọ, emi to si jẹ emi ni igba ikolẹ ẹ, to jẹ emi lo maa n ditẹ mọ, emi naa lo waa sa ba yii, emi lo n bẹ pe ki n ma jẹ ki wọn le oun nile ọkọ yii. Mo waa ri i pe yatọ si pe o fẹran iṣekuṣe, o laiki Alaaji gan-an ni, ko fẹẹ fi i silẹ rara, ko si fẹ ko foun silẹ, aye ẹ niyẹn.

Ẹni to ba ti fẹran ọkọ mi denudenu, ọrẹ mi ni o. O pẹlu ohun to jẹ ki n ran an lọwọ. Mo mọ pe Iya Dele fẹ ko ṣẹsin ni gbangba ni, bẹẹ tiẹ naa wa lara ẹ, abi oju wa nibi kọ loun ati wolii Sẹlẹ n fa a, ati ọkunrin to fẹẹ maa ra ọja lọwọ ẹ, ti iyẹn n jin in mọ ṣọọbu kan to wa nisalẹ Brown nigba yẹn. Tiẹ wa lara ẹ jare. Ohun ti mo ṣe kọkọ bu Aunti Sikira naa niyi, mo ni ko yee sunkun eke ati ẹkun iranu niwaju mi, pe ṣe bo ṣe dagba to yii, o fẹẹ sọ fun mi pe oun ko mọ pe agbere ko daa ni. Mo ni ti mo ba ti ran an lọwọ eleyii, lọjọ to ba tun ṣe bẹẹ, funra mi ni mo maa le e nile Alaaji. O loun fara mọ ọn, bi oun ba tun ṣe bẹẹ ki n le oun.

Mo fẹẹ fi oko kan pa ẹyẹ meji ni, nitori ẹ ni mo ṣe sọ fun un pe Safu lo maa ṣiṣẹ ọrọ to wa nilẹ yii o, mo ni mo maa ran an lọ sọdọ awọn famili Alaaji, pe oun lo maa lọọ da wọn duro ti wọn ko fi ni i wa mọ, nitori ti wọn ba pe famili le e lori ko ni i daa. Loun naa ba ni ki n ṣe bẹẹ, pe aburo oun kuku ni Safu, owu loun fi n ba a ja lẹẹkọọkan. Ni mo ba pe Safu, mo ni iyaale ẹ ni iṣẹ kan to jẹ oun lo maa ba a ṣe e. Ọmọ yẹn loun ti ṣetan to ba ti jẹ iṣẹ iyaale oun ni.

Ni mo ba ran Safu lọ si Agege ni ọjọ Jimọ, mo ni ko fun baba lowo, ko fun awọn Bọọda Lasisi ati awọn to ku ẹ lowo, pe ko waa ni ki Iya Walia waa ri mi. Ohun ti mo ni ko sọ fun wọn ni pe ipade ile Alaaji ko bọ si i mọ, mo ni ko ṣalaye fun baba pe ọrọ kekere gbaa ni, mo ni ma a yanju ẹ funra mi. Ọjọ yẹn naa ni mo pe Iya Walia pe ko waa ri mi. Asiko ti Safu wa l’Agege, Iya Walia wa lọdọ mi, mo dẹ ṣalaye fun un pe ko ma lọ sile ẹgbọn ẹ, ko dẹ ri i pe ko ṣeni to wa sipade kankan nile wa. Ni mo ba fun un lowo ọkọ, lo ba lọ. Bo ṣe jẹ pe lọjọ Satide, ko si famili kan to wa sile niyẹn o.

Leave a Reply