Awọn aṣofin yọ igbakeji gomina Ọyọ, wọn fi Bayọ Lawal rọpo rẹ

Monisọla Saka

Ni Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ yii, ni awọn aṣofin ipinlẹ Ọyọ yọ igbakeji gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinnia Raufu Ọlaniyan, ti wọn si fi Barisita Bayọ Lawal rọpo rẹ.

Lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹfa yii, ni awọn aṣofin fiwe waa wi tiẹ ranṣẹ si i, ẹsun marun-un ọtọọtọ ni wọn fi kan an. Wọn ni o ṣi ipo rẹ lo, o ṣe owo ilu baṣubaṣu ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Loootọ ni Ọlaniyan dahun si awọn ẹsun ti wọn fi kan an, to si gbe awọn aṣofin naa lọ sile-ẹjọ lati da wọn lọwọ kọ lori iyọnipo naa. Ṣugbọn kootu ko gba ẹbẹ rẹ.

Ni nnkan bii aago mọkanla kọja diẹ ni wọn fohun ṣọkan lati yọ ọ lori awọn ẹsun naa.

Lọdun 2019 ni wọn dibo yan Ọlaniyan gẹgẹ bii igbakeji gomina Ṣeyi Makinde to wa nipo bayii labẹ oṣelu PDP. Laipẹ yii lo fi ẹgbẹ naa silẹ, to darapọ mọ ẹgbẹ APC.

Oju ẹsẹ ni wọn ti fi baba ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin to ti figba kan jẹ kọmiṣanna eto idajọ ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ rọpo rẹ.

Leave a Reply