Adeleke bu sẹkun gbaragada nigba ti ajọ eleto idibo kede re bii gomina Ọṣun tuntun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Omije ayọ lo gba oju gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke, lẹyin ti ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọṣun kede rẹ gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo to waye lopin ọsẹ to lọ yii.

Ni ile ọkunrin naa to wa niluu Edẹ, nipinlẹ Ọṣun, loun atawọn gomina kan pẹlu awọn alatilẹyin rẹ mi-in, to fi mọ diẹ lara awọn ẹbi rẹ ti n wo bi gbogbo nnkan ṣe n lọ lori telifiṣan nipa eto naa.

Gẹgẹ bi fidio kan ti wọn ju sori ayelujara ṣe ṣafihan rẹ, ni gẹre ti adari ajọ eleto idibo Ọsun, Oluwatoyin Ogundipẹ kede Adeleke gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori, ọdọ ẹgbọn rẹ, Adedeji Adeleke,  iyẹn baba to bi Davido olorin taka-sufee, to jokoo lori aga ninu ile naa lo lọ, to dọbalẹ korobata, to si so mọ ọn. Ko le pa ayọ rẹ mọra, niṣe lo bu sẹkun, to si n nu omije naa nu bo ṣe so mọ ọkunrin yii.

Bẹẹ lo lọ sọdọ awọn gomina PDP to wa lori ijokoo nikọọkan, to n so mọ gbogbo wọn, to si n dupẹ lọwọ wọn.

Gbogbo awọn to wa nibẹ ni wọn fo fayọ, ti wọn si bẹrẹ si i pariwo, ‘imọlẹ, imọle’, bi ọkunrin naa ṣe n dunnu, to si n dupẹ lọwọ gbogbo wọn.Florence Babaṣọla

Leave a Reply