Awọn agbebọn kọ lu teṣan ọlọpaa ni Kogi, wọn pa insipẹkitọ, wọn tun dana sun ọkọ rẹpẹtẹ

Faith Adebọla
Ojumọ to mọ ni teṣan ọlọpaa to wa niluu Eika Ohizenyi, nijọba ibilẹ Okehi, ipinlẹ Kogi, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa yii, ki i ṣe ojumọ ire rara, afẹmọju ọjọ naa lawọn agbebọn ya bo teṣan naa, wọn pa ọga ọlọpaa to wa lẹnu iṣẹ nibẹ, wọn si dana sun gbogbo ọkọ ọlọpaa atawọn ọkọ mi-in to wa layiika teṣan ọhun.
Wọn ni gbara tawọn agbebọn naa ti de teṣan ọhun, niṣe ni wọn ṣina ibọn bolẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa gbiyanju lati doju ija kọ wọn. Lẹyin eyi ni wọn ju ado oloro ti wọn n pe ni dynamite, si teṣan naa, bi ado oloro naa si ṣe bu gbamu, niṣe ni apa kan ile naa ya lulẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi, William Ovye Aya, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Furaidee, sọ pe lasiko ti awọn ọlọpaa ati awọn afẹmiṣofo naa doju ibọn kọ ara wọn ni wọn pa inspẹkitọ ọlọpaa naa.
O lawọn agbebọn naa dana sun ọfiisi eria kọmanda, ati awọn ọkọ ọlọpaa, ọkọ adani atawọn dukia mi-in to wa layiika.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kogi, CP Edward Egbuka, ti ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ yii, o si ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn ọlọpaa adigboluja, ikọ ayara-bii-aṣa ti awọn ọtẹlẹmuyẹ, lọ sagbegbe naa.
Bakan naa ni wọn ti ko awọn ṣọja lọ sibẹ lati kun awọn oṣiṣẹ eleto aabo lọwọ.

Leave a Reply