Awọn ajinigbe pa iya agbalagba ti wọn ji gbe ni Benue, Ọṣun ti wọn sa wa lọwọ ti tẹ wọn

Florence Babaṣọla

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oṣun ti tẹ awọn ajinigbe mẹjọ labule Ọmọ-Ijeṣa. Ọjọ keje, oṣu karun-un ọdun yii lọwọ tẹ wọn lẹyin ti wọn ji iya agbalagba kan, Akiishi Catherine, gbe nipinlẹ Benue.

Awọn tọwọ ba ọhun ni Orikashima David, ẹni ọdun mejilelogun, Teryange Demenogo, ẹni ọdun mejilelogun, Terngu Tortindi, ẹni ọdun marundinlọgbọn, Anawuese Akough, ẹni ọdun mọkandinlogun, Mbalumulum Kaorga, ẹni ọdun mejidinlogun, Comfort Terdoo, ẹni ọdun mejilelogun, Micheal Msendoo, ẹni ọdun mọkandinlogun ati Aondoaseer Terver, ẹni ọdun mọkanlelogun.

Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, ṣe ṣalaye, ẹya Tivs, nipinlẹ Benue, lawọn mẹjẹẹjọ, lẹyin ti wọn si ji iya naa, ẹni ọdun marunlelọgọta gbe, wọn pa a sinu igbo nibẹ, wọn sa wa sipinlẹ Ọṣun ki ọwọ awọn agbofinro ma baa tẹ wọn.

Nigba ti wọn de Ọmọ-Ijeṣa, wọn bẹrẹ si i dunaadura pẹlu awọn mọlẹbi iya naa lori owo ti wọn yoo gba lati tu u silẹ lai jẹ ki wọn fura pe wọn ti pa a.

Asiko yii ni ọwọ kan ọwọ, ti aṣiri si tu pe ipinlẹ Ọṣun ni wọn wa, idi si niyẹn ti kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, Wale Ọlọkọde, fi ko awọn ikọ to ṣiṣẹ naa sodi funra rẹ, ti wọn si lọọ ru wọn jade nibi ti wọn sa pamọ si.

Ọpalọla sọ siwaju pe awọn eeyan naa jẹwọ pe o ti di eeyan mẹta tawọn pa ni iru ọna kan naa nipinlẹ Benue. O ni tiwadii ba ti pari lawọn yoo fa wọn le awọn ọlọpaa ipinlẹ Benue lọwọ.

Kọmiṣanna ọlọpaa gboṣuba fun awọn ọmọọṣẹ rẹ lori akitiyan wọn, o si tun fi da awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun loju pe ko ni i si ibikankan lati farapamọ si fun awọn ọdaran niwọn igba tawọn araalu ba ti fọwọsowọpọ pẹlu awọn ọlọpaa.

Nitori rogbodiyan to waye lawọn apa ibi kan nipinlẹ Ondo, awọn afurasi bii ogun ti wa lahaamọ ọlọpaa.

Leave a Reply