Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Awọn alaṣẹ ileewe giga Federal University Oye-Ekiti (FUOYE), ti sọ pe ki adari ẹka to n mojuto ohun to jẹ mọ akọsilẹ ati igbani-ṣiṣẹ (Registrar) nileewe naa, Ọgbẹni Ọlatunbọsun Odusanya, lọọ jokoo sile digba tiwadii yoo pari lori iwa to hu.
Ninu atẹjade kan ti Wọle Balogun, Oludamọran pataki lori eto iroyin fun ọga-agba ileewe naa fi sita, igbimọ alaṣẹ ti Ọmọwe Mohmmed Yahuza jẹ alaga fun lo gbe igbesẹ yii lati ṣewadii ẹsun gbigba awọn eeyan siṣẹ lọna aitọ, eyi ti wọn fi kan Odusanya.
Balogun ni, ‘‘Iwe gbele-ẹ ti wọn fun Odusanya tẹ ẹ lọwọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, Ọjọgbọn Abayọmi Faṣina ti i ṣe ọga-agba fasiti yii lo si fọwọ si i.
‘‘Lẹta naa sọ pe latari iwadii to n lọ lọwọ lori ọrọ gbigba awọn eeyan siṣẹ, eyi to fa lẹta wi-tẹnu-ẹ kan ti Odusanya ti kọkọ gba, ṣugbọn ti alaye to ṣe ko fẹsẹ mulẹ, lo fa ipinnu tuntun yii.’’
Fasiti ọhun ni ki Odusanya maa lọ silẹ na, bẹẹ ni yoo maa gba aabọ owo-oṣu, o si gbọdọ yọnda gbogbo nnkan fasiti naa to wa lọwọ ẹ, titi de ori kaadi idanimọ.
Ni bayii, FUOYE ti yan Ọgbẹni Mufutau Ibrahim gẹgẹ bii adele si ipo ti Odusanya wa tẹlẹ.