Awọn alaga kansu ti Makinde le danu fẹyin ẹ janlẹ ni kootu, adajọ ni ko sanwo itanran

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn alaga kansu ti ilu dibo yan kaakiri ijọba ibilẹ mẹtẹẹtalelọgbọn (33) ni ipinlẹ Ọyọ, lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC, ti la gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, mọlẹ ninu ẹjọ ti wọn pe ta ko oun ati ijọba rẹ lori bo ṣe le wọn kuro lori aleefa gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ kaluku wọn.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keje, oṣu karun-un, ọdun 2021 yii, nile-ẹjọ to ga ju lọ lorileede yii ti gbe idajọ naa kalẹ.

Tẹ o ba gbagbe, lọdun 2018, nigba ti saa iṣejọba to kọja n lọ sopin, ni gomina ipinlẹ Ọyọ nigba naa, Oloogbe Abiọla Ajimọbi, ṣeto idibo ijọba ibilẹ, ninu eyi to jẹ pe gbogbo awọn to dupo alaga kansu ati kansilọ lorukọ ẹgbẹ oṣelu gomina naa, APC lo jawe olubori.

Ṣugbọn lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2019, lọjọ ti Ẹnjinnia Makinde gbọpa aṣẹ gẹgẹ bii gomina tuntun, lo ti le awọn eeyan yii danu, to si yan awọn alaga afun-n-ṣọ ti wọn n pe ni kiateka sipo gbogbo wọn.

Latigba naa lawọn ti wọn yọ nipo yii ti tẹsẹ bọ ṣokoto ija pẹlu ijọba. Ọmọ ọba Abass Ayọdeji Aleṣinlọyẹ to jẹ olori awọn alaga kansu ilẹ yii, ALGON, ni ipinlẹ Ọyọ lo ṣaaju ija naa gẹgẹ bii olori wọn.

Awijare wọn nile-ẹjọ giga to wa niluu Ibadan ni pe ofin ilẹ yii ko fun gomina lagbara lati yọ ẹnikẹni ti awọn araalu ba dibo yan nipo. Nitori naa, ki ile-ẹjọ fagi le igbesẹ gomina naa, ki wọn si da awọn pada sipo awọn kia.

Niwọn igba ti Gomina Makinde ati igbimo iṣijọba rẹ naa ko ti kawọ gbera duro lori ọrọ yii, ẹbi, eyi ti ewurẹ n jẹ bọ nisọ gaari lawọn olupẹjọ naa jẹ ninu ẹjọ ko-tẹmi-lọrun to waye lọdun 2020. Eyi lo si mu ki awọn alaga kansu naa gba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ yii lọ fun idajọ alaiṣegbe.

Ninu idajọ ọhun to waye niluu Abuja lọjọ Ẹti, ni nnkan ti ṣẹnuure fawọn olupẹjọ wọnyi pẹlu bi ile-ẹjọ naa ṣe da wọn lare, to si ṣapejuwe igbesẹ ti Gomina Makinde gbe gẹgẹ bii ohun to lodi sofin jọjọ.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ko fọwọ si i pe ki awọn eeyan naa pada si ọfiisi koowa wọn, wọn ni asiko to yẹ ki wọn fi wa nipo ti kọja lọ, sibẹ, igbimọ awọn agba adajọ naa paṣẹ fun Makinde lati san miliọnu lọna ogun Naira (₦20m) gẹgẹ bii owo itanran fun iwa aibofinmu to hu.

Bakan naa ni wọn paṣẹ fun un lati san gbogbo owo-oṣu ati ajẹmọnu to yẹ ki wọn gba ni gbogbo asiko ti ijọba yii ko jẹ ki wọn ti lo nipo.

Leave a Reply