Tusidee to n bọ ni wọn yoo sinku ọmọ Baba Adeboye

Bi gbogbo nnkan ba lọ bi wọn ṣe ṣeto rẹ, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to n bọ ni wọn yoo sinku Pasitọ Deji Adeboye, ọmọ Olori ijọ Ridiimu, Pasitọ Adejare Adeboye.

Ninu atẹjade kan ti aburo oloogbe naa to tun jẹ oluranlọwọ pataki fun Baba Adeboye, Leke Adeboye, fi sita lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, lo ti ni ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹsan-an, oṣu yii, ni isin pataki yoo waye fun oloogbe naa ni City of David Youth Church, Eket, nipinlẹ Akwa Ibom.

Ni Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu yii, kan naa ni isin pataki ati ọrọ iwuri nipa oloogbe yoo waye ni RCCG, House of Favour, Redemption Camp.

Ọjọ kọkanla, oṣu yii, ni deede aago mẹwaa aarọ, ni isin idagbere yoo waye Youth Centre, Redemption Camp, nipinlẹ Ogun. Lẹyin eyi ni wọn yoo fi eeru fun eeru, yeepẹ fun yeepẹ.

Leke fi ẹmi imoore rẹ han fun adura, aduroti ati atilẹyin ti awọn eeyan n fi ranṣẹ latigba ti iṣẹlẹ ibanujẹ naa ti ṣẹlẹ. O ni awọn mọ riri atilẹyin awọn eeyan. Ohun to si dun mọ awọn ninu ni pe arakunrin awọn ti lọ sọdọ Olugbala lati sinmi laya Ẹledaa rẹ.

O ni igbe aye rere ti Dare gbe ati fifi ara jin fun iṣẹ Ọlọrun jẹ ohun idunnu fun awọn.

Leave a Reply