Awọn eeyan fẹhonu han niluu Ọrẹ lori ọwọngogo epo ati owo Naira tuntun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọgọọrọ awọn ọdọ ni wọn tu jade niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lati fẹhonu han lori ọrọ ọwọngogo epo bẹntiroolu ati owo Naira eyi to n ba awọn eeyan fínra.

Ọpọlọpọ wakati lawọn lawọn tinu n bi naa fi di oju ọna pa, ti  ọkọ pẹlu awọn arinrin-ajo to n gba oju ọna marosẹ Ọrẹ si Benin, ko fi raaye kọja lasiko ti ifẹhonu alaafia naa fi waye.

Awọn olufẹhonu naa ni wọn kọ jalẹ lati tẹle ikilọ ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ṣe ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii kan naa.

Ọkan ninu awọn olufẹhonu han ọhun, Ọmọọba Adebayọ Adeyẹmi, ṣalaye fun akọroyin wa pe ni iṣoro tawọn eeyan n koju lọwọlọwọ latari ọrọ ọwọngogo epo ati airi owo Naira na ti n kọja ifarada.

Aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee lawọn ọdọ kan ti kọkọ ko ara wọn jọ si orita Adegbọla, niluu Akurẹ, lati fẹhonu han lori wahala ti wọn n koju nileefowopamọ kan to wa lagbegbe naa, ṣugbọn wọn ko ti i bẹrẹ iwọde naa ti awọn ọlọpaa kan fi waa tu wọn ka.

Eyi lo ṣokunfa ipade pajawiri ti Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Oyeniran Oyeyẹmi, sare pe, nibi to ti kilọ fawọn to n gbero lati fẹhonu han pe ohun ti ko ni i ṣee ṣe ni, nitori awọn ko ni i laju awọn silẹ ki awọn janduku kan ja iwọde naa gba mọ wọn lọwọ.

 

 

 

Leave a Reply