Awọn Fulani da maaluu wọ ọgba ileewe Poli, lawọn ọlọpaa ba fofin mu wọn ni Ṣaki

Olu-Theo Ọmọlohun, Oke-Ogun

Niṣe lọrọ di bo-o-lọ-o-yago ninu ọgba ileewe Poli Oke-Ogun to wa nipinlẹ Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, nigba tawọn maaluu rẹpẹtẹ ṣadeede ya bo ọgba ileewe naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ti wọn si ṣediwọ fun eto ẹkọ to n lọ lọwọ.

ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe awọn agbẹ kan ni wọn le awọn Fulani naa pẹlu maaluu wọn l’Abule Amodu, ti ko fi bẹẹ jinna sileewe ọhun, eyi lo mu ki wọn kọri sileewe naa.

Ọgbẹni Kareem to jẹ ọga awọn sikiọriti ileewe poli ọhun sọ pe o ti to bii ọjọ mẹta tawọn ti n ṣakiyesi awọn maaluu to n rin regberegbe ọhun layiika ileewe wọn, tawọn ko si ri awọn Fulani to n dari wọn.

O ni iyalẹnu lo jẹ bi awọn maaluu naa ṣe ya bo ọgba ileewe naa, ti wọn si lọọ dara pọ mọ awọn maaluu tileewe naa n sin lati ṣedanilẹkọọ fawọn akẹkọọ wọn.

Iṣẹlẹ ojiji yii lo mu kawọn akẹkọọ ati olukọ bẹ jade, ti kaluku si wa ọna lati fi ọgba ileewe naa silẹ, tori niṣẹ lawọn maaluu ọhun fẹẹ wọnu yara ikawe.

Kareem lawọn ranṣẹ sawọn agbofinro loju-ẹsẹ, o ni bawọn ọlọpaa ṣe de ni wọn bẹrẹ si i tọpasẹ ẹni to le da awọn maaluu naa gba agbegbe ọhun.

Wọn ni Gaa Fulani Amodu lawọn afurasi ọdaran ti wọn ni maaluu naa wa, ibẹ lawọn ọlọpaa ti ri wọn, ti wọn si fi pampẹ ofin gbe wọn fun iwa aibikita ati ọbayejẹ ti wọn hu ọhun.

Gẹgẹ bi Kareem ṣe wi, lẹyin ọpọ ẹbẹ, awọn alaṣẹ ileewe naa gba lati tọwọ bọwe adehun alaafia pẹlu awọn Fulani onimaaluu yii, wọn si kilọ gidi fun wọn lati ma ṣe san aṣọ iru ẹ ṣoro mọ.
Ninu iwe adehun naa, awọn Fulani fọwọ si i pe awọn gba pe ajoji lawọn, ati pe ọrọ to le mu awọn foju bale-ẹjọ ni ti maaluu wọn ba jẹko ni ibi ti ko yẹ, tabi to ba dukia ati oko ẹlomi-in jẹ.

Leave a Reply