Awọn Fulani darandaran pa eeyan rẹpẹtẹ, wọn sun awọn kan mọnu mọto, nijọba ibilẹ Ọsẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ko din leeyan mẹfa ti wọn pade iku ojijj lasiko tawọn Fulani afẹmiṣofo kan lọọ kọ lu awọn ileto kan nijọba ibilẹ Ọsẹ, laarin ọsẹ to kọja.

Lara awọn ileto ta a gbọ pe wọn n koju ọkan-o-jọkan akọlu tawọn darandaran ọhun n ṣe lati bii ọsẹ meji sẹyin ni Arimọgija, Mọ́légé pẹlu awọn meji miiran.

Ọkan pataki lara awọn aṣaaju agbegbe naa, Ọgbẹni Owolafẹ Fọlọrunṣọ to ba ALAROYE sọrọ ni ohun to ṣokunfa akọlu tawọn agbebọn n ṣe lọwọlọwọ laọn agbegbe ọhun ko sẹyin bi awọn agbẹ kan ṣe pinnu lati gbe igbesẹ ta ko bi awọn Fulani to n daran ṣe n ba awọn nnkan ọgbin olowo iyebiye ti wọn foogun oju wọn ṣiṣẹ fun jẹ.

O ni ọpọ ire oko to yẹ kawọn fi ṣe anfaani lawọn ti padanu sọwọ awọn darandaran wọnyi pẹlu bi wọn ṣe maa n fi oru boju da maaluu wọ inu oko awọn, ti wọn yoo si maa fa awọn nnkan ọgbin ti awọn ti gbin tu fun awọn ẹran wọn lati jẹ.

Nibi tawọn bororo ọhun daju de, aimọye igba lo ni wọn ti lọọ ka awọn agbẹ kan mọ inu oko wọn pẹlu ibọn, ti wọn yoo ṣi fipa mu wọn lati maa fọwọ ara wọn tu awọn ire oko wọn fun awọn maaluu ti wọn da wọnu oko oloko jẹ.

O ni nigba tọrọ yii fẹẹ maa le ni aleju ni awọn lọọ fẹjọ awọn Fulani ọhun sun awọn ẹṣọ alaabo, ti wọn si gbe igbesẹ kiakia lati waa ba awọn le awọn baṣejẹ obi ti i so lẹẹrun naa kuro ninu oko awọn.

Eyi lo ni o bi awọn ẹni ibi naa ninu ti wọn fi lọọ ko ara wọn jọ, ti wọn si pada wa laarin oru pẹlu ibọn AK47, ada, aake atawọn nnkan ija mi-in lati waa ṣe akọlu nla si awọn araalu, ninu eyi ti ọpọ awọn eeyan ku si.

Ọgbẹni Fọlọrunṣọ ni ọsan gangan lawọn Fulani ọhun tun lọọ dena de awọn arinrin-ajo kan lasiko ti wọn n pada bọ lati Akurẹ, gbogbo awọn eeyan ọhun lo ni wọn pa, ti wọn si tun dana sun ọkọ wọn lẹyin ti wọn ti ji owo atawọn ẹru wọn ko.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ọkan ninu awọn ọba alaye nijọba ibilẹ Ọsẹ, Onimoru ti Ìmòru, Ọba Rotimi Ọbamuwagun, ni ko si ani-ani pe inu ewu nla lawọn wa latari itu buruku tawọn Fulani n fi awọn eeyan pa ni gbogbo igba.

O ni laipẹ yii lawọn Fulani kan lọọ fi maaluu ba oko ẹgẹ to to bii sare ilẹ mẹrin jẹ, oko naa lo ni o jẹ ti ọkan lara awọn eeyan ilu Ìmòru, ẹni to lọọ yawo nla ni banki lati fi da oko ọhun.

Obidiado ti Ilu Ìjàgbà, Ọba Andrew Ikioya, ninu ọrọ tirẹ ni nibi ti aaye gba awọn darandaran naa de, wọn ti n lọ sinu oko oloko lati lọọ kore nnkan ọgbin wọn, wọn yoo si tun ru u wa sinu ọja waa ta, ti oloko ko si lori laya ko sọrọ tabi ko da wọn lẹkun.

Awọn ọba alade mejeeji yii ni kayeefi lo ṣi n jẹ fawọn eeyan idi tijọba apapọ fi n gba awọn Fulani wọnyi laaye lati maa gbe ibọn AK47 kiri, eyi ti wọn fi n dunkooko mọ awọn araalu.

Bakan naa lawọn ori-ade ọhun tun gbe oṣuba nla fun Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, lori ṣiṣe agbekalẹ ẹṣọ Amọtẹkun fun aabo ẹmi ati dukia awọn araalu.

Alaga ijọba ibilẹ Ọsẹ, Ọmọọba Adekunle Dennis, lasiko to ṣe abẹwo si awọn ileto ti wọn ṣe akọlu si ba ẹbi awọn to fara gba ninu iṣẹlẹ naa kẹdun.

O ni ẹdun ọkan patapata lawọn iṣẹlẹ akọlu gbogbo igba to saaba maa n waye nijọba ibilẹ Ọsẹ n jẹ fun Gomina Akeredolu bẹẹ lo rọ ijọba lati tete wa ọna abayọ si awọn ipenija eto aabo ọhun ki nnkan too bọwọ sori.

Nigba ti akọroyin wa kan si Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, lori aago, o ni ko si ọrọ akọlu ṣiṣe lori iṣẹlẹ naa, bo tilẹ jẹ pe loootọ lawọn eeyan agbegbe ohun waa fẹjọ sun lọdọ awọn pe awọn kan waa ya bo awọn.

O ni loju ẹsẹ lawọn ẹṣọ alaabo si ti lọ síbẹ ki alaafia le jọba.

 

Leave a Reply