Micheal yinbọn fun ọrẹkunrin aburo ẹ, o loun ko fẹ ko fẹ ẹ

Gbenga Amos, Abẹokuta

Boya orin ‘Micheal wa lo ida ẹ’ tawọn oniṣọọṣi n fi orukọ ẹ kọrin, lo pa a bii ọti ni o, boya inu abisodi naa lo si ru bo o loju to bẹẹ, ọkunrin ẹni ọgbọn ọdun ti wọn porukọ ẹ ni Micheal Ogundele yii nikan lo le ṣalaye ara ẹ, o si ti n ṣalaye ọhun lakolo awọn ọlọpaa, latari bo ṣe fibinu yinbọn lu ọrẹbinrin aburo ẹ kan, Tobi Ọlabisi, o loun o fẹ wọle-wọde ẹ pẹlu aburo oun, oun si ti kilọ fun un, ko fẹẹ jawọ.

Aafaa Akeem, to jẹ ọkan ninu awọn aṣaaju ẹsin niluu Ihunbọ, lo lọọ fi iṣẹlẹ ọhun to wọn leti lẹka ileeṣẹ ọlọpaa Idiroko lọjọ keji, oṣu Keji, ta a wa yii, pe afurasi naa ti yinbọn lu Tobi o, ọkunrin naa ko ti i ku, amọ awọn ti gbe e digbadigba lọ si ọsibitu, tori niṣe lẹjẹ n da lara ẹ bii omi, bo maa ye tabi o maa ku, awọn o ti i mọ.

Lọgan ti DPO teṣan Idiroko, CSP Ayọ Akinṣọwọn, gbọ sọrọ yii lo ti paṣẹ pe kawọn ọmọọṣẹ ẹ lọọ fi pampẹ ofin gbe Micheal, Ọlọrun si ba wọn ṣe e, wọn ka a mọ ibi to sa pamọ si, ni wọn ba fọwọ ṣinkun ofin gbe e.

Nigba to de teṣan ti wọn beere bọrọ ṣe jẹ ko too dogun a n yinbọn mọra ẹni, afurasi naa ni o ti pẹ toun ti n gbọ finrin-finrin pe Tobi n ṣe kurukẹrẹ lọdọ aburo oun obinrin ti wọn forukọ bo laṣiiri, ọmọ ọhun si n kawe lọwọ, nigba toun si wadii, toun ri i pe loootọ ni, oun pe Tobi, oun si kilọ fun un gidigidi pe ko wa ọrẹbinrin ẹ siwaju, aburo oun ko si fun iranu, oun ko fẹ ajọṣe wọn.

Amọ, o lọmọkunrin naa ko jawọ, ko si yee wa aburo oun wa, bẹẹ lo maa n rẹburu ẹ kiri igboro, o lọrun iṣu laparo i ku si.

O ni lọjọ tiṣẹlẹ naa waye, awọn kan ni wọn waa yin in soun leti pe Tobi tun ti yọ kẹlẹ wọle sinu yara aburo oun, wọn ni afaimọ ni wọn o ti ma ṣe ‘kerewa’ funra wọn, loun ba dide lati lọọ wo o boya loootọ ni, oun si gbe ibọn ṣakabula kan dani.

O ni nigba toun debẹ, toun wọnu yara naa, niṣe loun ba Tobi lori bẹẹdi aburo oun to sunkaaka, amọ bo ṣe yira pada to ri oun lo fo dide, o wo raa-raa-ra, o n wọna lati sa lọ, igba to ri i pe ẹnu ọna ko ṣee gba foun tori ibẹ loun duro si, lo ba ta mọ windo, o fẹẹ gbabẹ bẹ jade, oun fa a laṣọ, ṣugbọn ọwọ oun ko to o daadaa to fi bẹ sodikeji, eyi lo jẹ koun dana ibọn ya a, tori oun ko fẹ ko sa lọ, oun si fẹẹ kọ lọgbọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’Alaroye sọ pe wọn ti gbe ọkunrin to yinbọn mọ naa lọ ọsibitu Jẹnẹra Idiroko, wọn nibẹ lo ṣi wa di ba a ṣe n sọ yii, ti wọn n tọju ẹ, boya yoo le ru u la.

O ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, naa ti gbọ nipa iṣẹlẹ yii, o si ti paṣẹ pe ki wọn taari Micheal yinbọn-yinbọn ati ibọn ẹ si ẹka ti wọn ti n tọpinpin iwa ọdaran abẹle, ki wọn le tubọ ṣewadii lẹkun-un rẹrẹ.

Wọn ni lẹyin iwadii, afurasi naa yoo kawọ pọnyin niwaju adajọ.

Leave a Reply