Awọn janduku ṣe oṣiṣẹ panapana ati ṣọja leṣe nibi ijamba ina kan n’Ilọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni awọn janduku kan kọ lu ajọ panapana ati awọn ọmọ ogun ilẹ wa kan nibi ti wọn ti fẹẹ pana to n jo ni ileepo K&R, leyii to fi ọpọlọpọ dukia ṣofo. Awọn oṣiṣẹ panapana meji lo fara pa yanna-yanna lagbegbe Oke-Agodi, Alfa Yahaya, Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹfa aṣaalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni ina kan sọ nileepo K&R. Lasiko ti wọn n da epo bẹntiroolu ti wọn lọọ ra lati inu durọọmu sinu tanka ọkọ ayọkẹlẹ kan ati ọkọ bọọsi ti wọn n ko epo naa ni ina sọ, ti awọn mọto yii si jona raurau ko too di pe awọn panapana dẹbẹ.

Awọn aladuugbo tọrọ naa ṣoju wọn sọ pe ohun to da wahala silẹ ni awọn eeyan ti wọn n fi omi inu ọra pana ki awọn panapana too de, ti wọn si lo anfaani naa lati ji owo atawọn nnkan miiran ko nileepo naa, eyi ti wọn pe ni owo wahala ti wọn ṣe lati ri i pe wọn pana naa.

Bayii ni wọn bẹrẹ si i sọko mọ awọn oṣiṣẹ panapana yii, eyi lo mu ki ẹni to ni ileepo naa pe awọn ọmọ ologun fun aabo.

Ṣugbọn awọn ọmọta naa ko tori ẹyi sinmi, lasiko wahala naa ni wọn fi oko fọ sọja kan lori ti ẹjẹ si n da ṣoroṣoro lara rẹ. Ibọn lawọn ṣọja naa yin soke ti wọn fi tu awọn janduku naa ka.

Alukoro ajọ panapana ni Kwara, Hassan Hakeem Adekunle, sọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ naa meji lo fara pa nigba tawọn janduku naa kọ lu wọn, ṣugbọn wọn pada pa ina naa patapata, wọn si daabo bo dukia to n lọ bii miliọnu mẹrin lọwọ ina.

Leave a Reply