Awọn ọlọpaa ti ko rowo oṣu gba l’Ọṣun ni: Awọn ọlọkada lo n fẹyawo wa bayii

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn olọpaa kan ti wọn le die diẹ ni ẹẹdẹgbẹta ni wọn fọn soju popo l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lasiko ti wọn n ṣewọde lori  bi ijọba ko ṣe san owo-oṣu fun wọn.

Lati Oke-Fia ni wọn ti gbera kọja si orita Ọlaiya, niluu Oṣogbo, bi wọn ṣe gbe oniruuru akọle lọwọ ni wọn n kọrin.

Wọn ni ijọba ko ti i fun awọn lowo kankan lati oṣu Karun-un, ọdun 2021, tawọn ti pari idanilẹkọọ iṣẹ aabo naa, eleyii si ti n ṣakoba pupọ lori ọrọ aje awọn.

Lara awọn akọle ti wọn gbe lọwọ ni: “Awọn ọlọkada ni wọn n ba awọn iyawo wa sun”, “Ẹ sanwo oṣu wa kiakia”, “Ẹ sanwo oṣu ati ajẹmọnu wa”, “Odidi oṣu mejidinlogun lai gba kọbọ” ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọkan lara wọn to ba awọn oniroyin sọrọ ṣalaye pe ṣe lawọn n fi ẹmi laku pẹlu iṣẹ naa, o ni awọn mẹta lawọn ti padanu laarin oṣu mejidinlogun naa; awọn meji niluu Ikire, ẹni kan niluu Iree.

Ọkunrin knọstabulari yii ṣalaye pe oniruuru igbesẹ lawọn ti gbe lati le jẹ kijọba sanwo oṣu fun awọn, o ni awọn ti lọ sọdọ awọn alaga ijọba ibilẹ, bẹẹ lawọn ti de ọdọ awọn aṣofin, ṣugbọn pabo lo ja si.

Nigba to n ba awọn olufẹhonu han naa sọrọ, Kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, Wale Ọlọkọde, paṣẹ pe ki wọn dawọ ifẹhonu han naa duro kiakia, o ni ko bojumu ki wọn wa ninu aṣọ afarajọlọpaa, ki wọn si maa di alaafia awọn araalu lọwọ pẹlu ifẹhonu han.

Ọlọkọde waa ṣeleri pe ẹdun ọkan wọn yoo de ọdọ awọn alaṣẹ.

Leave a Reply