Baba Ijẹṣa pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, o ni ki wọn foun ni beeli lẹwọn

Faith Adebọla, Eko

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ yii, ni ile-ẹjọ akanṣe to n gbọ ẹsun ifipa ba ni lọ pọ ati iwa ọdaran abẹle yoo yiri ẹbẹ gbaju-gbaja adẹrin-in poṣonu onitiata ilẹ wa nni, James Ọlanrewaju Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa wo, lati pinnu boya ki wọn fun ọkunrin naa ni beeli, ko le maa tile ẹ waa jẹjọ, tabi ki wọn ṣi se e mọ ẹwọn Kirikiri to wa  titi ti igbẹjọ lori ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to pe yoo fi pari.

Ọjọ naa ni Adajọ Oluwatoyin Taiwo yoo pinnu boya loootọ ni Baba Ijẹṣa kunju oṣuwọn ẹni ti wọn le faaye beeli silẹ fun, lẹyin to ti lo, o kere tan, oṣu meji ninu ẹwọn ọdun marun-un ti wọn da fun un.

Lara ohun ti wọn yoo gbe yẹwo ni boya iwe ipẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun rẹ bọ saarin gbedeke ọsẹ mẹta ti ofin la kalẹ fun ẹni to ba fẹẹ pẹjọ ta ko idajọ ile-ẹjọ giga. Wọn yoo tun wo o boya ẹlẹwọn naa ni akọsilẹ rere lọgba ẹwọn, ti ko si ti i fo beeli ri, atawọn nnkan mi-in.

Nigba ti ọrọ ipẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun Baba Ijẹṣa jẹ yọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹsan-an yii, agbẹjọro Baba Ijẹṣa, Amofin Chukwudi pe akiyesi adajọ si ẹbẹ onibaara rẹ pe kile-ẹjọ ṣaanu oun, o ni ki wọn faaye beeli silẹ fun un, ni ibamu pẹlu isọri kẹfa, ila kẹfa iwe ofin ilẹ wa, ati isọri kọkanlelaaadọta, ofin eto idajọ tile-ẹjọ giga nipinlẹ Eko, eyi to fun adajọ lagbara lati faaye beeli silẹ fun ẹlẹwọn to pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun.

Lọọya naa ṣalaye niwaju adajọ pe, idi pataki tawọn ṣe gbe ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ọhun wa siwaju rẹ ko ṣẹyin awọn ipenija kan to jẹ yọ. O ni lọwọlọwọ yii, nigba tawọn wo kalẹnda ati awọn ẹjọ to wa niwaju kootu ko-tẹ-mi-lọrun daadaa, awọn ẹjọ naa pọ gidi debii pe ti wọn ba tun fi ti Baba Ijẹṣa kun un, ko sigba ti ọdaran naa ko ti ni i pari ẹwọn rẹ ki igbẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun too bẹrẹ, tori ọdun mẹta aabọ pere ni ẹwọn ọdun marun-un ti wọn wọn fun onibaara oun ku si, nibaamu pẹlu onka ati kalẹnda ti wọn n fi n kajọ fawọn ẹlẹwọn.

Chukwudi ni ti wọn ba si wo o daadaa, ki wọn beere ọrọ wo lọwọ awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn, wọn maa jẹ́rìí si pe eeyan daadaa ni Baba Ijẹṣa o, iwa jẹẹjẹẹ lo n hu lẹwọn, ko si da awọn wọda to n ṣọ wọn laamu rara, o lọmọluabi ni lọhun-un.

O ni tori ẹ lawọn ṣe rọ ile-ẹjọ naa lati ṣiju aanu wo onibaara oun, ki wọn gba tiẹ ro, ki wọn si ro tọmọluabi mọ ọn lara, ki wọn fun un ni beeli naa.

Ṣugbọn agbẹjọro fun ijọba fo dide loju-ẹsẹ, Amofin Ọmọwunmi Bajulaiye Bishi, sọ pe oun o gba ohun ti olujẹjọ n sọ lẹnu yẹn, oun o si fara mọ ẹbẹ fun beeli rẹ, o ni ko si ipo pataki, tabi ipenija àkànṣe kan tile-ẹjọ fẹẹ ro mọ ẹlẹwọn naa lara, tori ko rọ lapa, ko si fọ loju, bẹẹ ni ko si akọsilẹ kankan pe aarẹ mu un lẹwọn, ọrọ beeli ti waa jẹ? O ni kile-ẹjọ wọgi le ẹbẹ Baba Ijẹṣa fun beeli, ọgba ẹwọn to wa yẹn naa ni ko ti maa jẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ẹ, bo tilẹ jẹ pe oun o lodi si ìpéjọ rẹ tuntun yii, o lo lẹtọọ si ipẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun labẹ ofin.

Tẹ o ba gbagbe, Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun yii, lorukọ Ọlanrewaju Omiyinka, wọwe awọn ọdaran afipa ba ni lo pọ nipinlẹ Eko, latari idajọ ile-ẹjọ kan naa yii to da a lẹbi leyin to ti rojọ, tẹnu ẹ ti fẹrẹ bo fun ọdun kan gbako. Wọn lẹrii fihan pe loootọ lo huwa ainitiju, iwa iṣekuṣe pẹlu ọmọọdun mẹrinla kan to n gbe ile Damilọla Adekọya tawọn eeyan mọ si Princess, wọn ni ko lọọ fẹwọn jura, ko le kọgbọn.

Ṣa, Adajọ Oluwatoyin Taiwo ti ni kawọn olujẹjọ ati olupẹjọ naa pade oun lọjọ Aje, Mọnde, to n bọ yii.

Leave a Reply