Iṣẹ ti wọn yan fun INEC lati ṣe labẹ ofin ju agbara wa lọ – Yakubu

Faith Adebọla, Eko

Ọga agba ajọ INEC to n ṣe kokaari eto idibo nilẹ wa (Independent Electoral Commission), Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, ti sọ pe ipenija nla lọrọ awọn ti wọn n da eto idibo ru, paapaa awọn to n fowo ra ibo, o ni kiru iwa bẹẹ atawọn iwa abeṣe mi-in to n waye lasiko eto idibo too le dẹkun, afi kijọba ro ajọ NIEC lagbara, ki wọn si fofin ti i nidii, ki ajọ naa le maa gbe awọn to lọwọ ninu iwakiwa kawọ pọnyin rojọ, ati pe labẹ ofin ti INEC fi n ṣiṣẹ lọwọlọwọ yii, ẹru to ju agbara ajọ naa lọ ni wọn gbe le e lejika.

Mahmood sọrọ yii lasiko to n dahun ibeere tawọn oniroyin bi i nibi apero ọlọjọ mẹta kan ti wọn gbe kalẹ lati ṣatunyẹwo eto idibo sipo gomina to waye nipinlẹ Ekiti ati Ọṣun laipẹ yii, pẹlu erongba lati mọ awọn igbesẹ ti yoo pọn dandan fun wọn lati gbe ki eto idibo ọdun 2023 le tubọ mọyan lori, ko si ṣetẹwọgba faraalu.

Ifikun-lukun naa waye lowurọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹsan-an yii, ni gbọngan apero Raddison Blu Hotel, to wa n’Ikẹja, nipinlẹ Eko.

Mahmood to sọrọ ikini kaabọ lati ṣide apero naa sọ pe gbogbo igba ti INEC ba ti ṣeto idibo lawọn maa n ṣatunyẹwo bi eto idibo naa ba ṣe lọ si, ki wọn le mọ awọn ipenija ati bo ṣe ku diẹ ka-a-to si, tori a ki i mọ ọn rin ki ori ma mi, eyi yoo si jẹ ki awọn wa atunṣe si i. Bẹẹ lawọn yoo wo ibi ti awọn ti ṣe aṣeyọri, ki awọn le tubọ tẹra mọṣẹ lapa ibẹ.

Ọga INEC yii ṣalaye fawọn oniroyin pe, “Ohun to le wagbo dẹkun fawọn janduku, atawọn to n ṣe agbodegba fawọn oloṣelu ni kijọba ṣedasilẹ ajọ kan ti yoo maa ṣe kokaari igbokegbodo INEC, ti yoo si tun lagbara lati wọ awọn afurasi arufin idibo lọ sile-ẹjọ, ko si fiya jẹ wọn labẹ ofin, iyẹn National Electoral Offenses Commission and Tribunal.

“A ti sọ ọ lọpọ igba pe iṣẹ ti ofin fun INEC laṣẹ lati ṣe ju agbara wa lọ. Fun apẹẹrẹ, ofin fun INEC laṣẹ lati wọ arufin eto idibo lọ sile-ẹjọ, bẹẹ keeyan too le wọ ẹnikan lọ sile-ẹjọ, tọhun gbọdọ kọkọ ni ẹtọ ati agbara lati faṣẹ ọba mu ni.

“INEC ko lọlọpaa tiẹ, a o ni ẹṣọ alaabo to jẹ tiwa, a o si lagbara lati mu afurasi ọdaran funra wa, afi ta a ba ṣẹṣẹ ke sawọn ọlọpaa atawọn agbofinro mi-in. Bo tilẹ jẹ pe ofin fun oluṣekokaari idibo to n lọ lọwọ ni ibudo eto idibo kọọkan laṣẹ lati fofin mu’ni, ṣe asiko ti oluṣekokaari n ka ibo, to n mojuto ọrọ awọn oludibo lọwọ ni yoo maa ṣọ ẹni to fẹẹ fowo ra ibo abi awọn arufin mi-in?

“Ni idakeji, INEC ko ni awọn irinṣẹ iwadii, a o si ni awọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn maa tọpinpin lati ko ẹri jọ, eyi to maa jẹ ka le ro arojare lori afurasi arufin ta a ba wọ lọ sile-ẹjọ, bi iwadii ati ẹri ko ba si fẹsẹ rinlẹ, ile-ẹjọ maa da ẹjọ nu ni.

“Ohun mi-in ti mo ti sọ lọpọ igba ni pe nigba mi-in, o le jẹ awọn oṣiṣẹ tiwa gan-an ni wọn maa rufin eto idibo, awọn kan si le gbabọde lara wọn, o maa ṣoro fun INEC lati gbe iru oṣiṣẹ rẹ yii lọ sile-ẹjọ, tori bii igba ti INEC n wọ INEC lọọ si kootu niyẹn jẹ. Ṣugbọn ti iru ajọ akanṣe to n gbọ ẹsun idibo bẹẹ ba wa, yoo ṣee ṣe lati mu ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun idibo, ibaa jẹ oṣiṣẹ wa tabi ẹlomi-in.

“Eyi to ja ju lọ ninu gbogbo ẹ ni pe, awọn to n ṣonigbọwọ fun iwa irufin eto idibo yii gan-an la gbọdọ ṣawari wọn, ka si fi pampẹ ofin gbe wọn. Janduku to waa ja apoti ibo gba ko si lara awọn to n dije, orukọ ẹ ko si ninu awọn ti wọn fẹẹ dibo fun, ẹnikan lo ra an niṣẹ buruku yẹn, iromi to n jo lori omi loun, onilu ẹ wa nisalẹ odo, a ni lati wa ẹni to ra an niṣẹ kan, ka si ba wọn ṣẹjọ, ki wọn fimu kata ofin. Igba yẹn lawọn olubi maa sunra ki, ti iwa irufin idibo yoo rọlẹ,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Awọn kọmiṣanna ajọ ọhun kaakiri ipinlẹ gbogbo atawọn lọgaa-lọgaa lọkunrin lobinrin nileeṣẹ naa, ti iye wọn fẹrẹ to ọgọrun-un, lo pesẹ sibi apero naa.

Kọmiṣanna ajọ INEC nipinlẹ Eko, Ọnarebu Oluṣẹgun Agbaje, sọ f’AKEDE AGBAYE  ninu ifọrọwerọ ta a ṣe pẹlu rẹ pe lẹyin apero yii, eto ilanilọyẹ to maa tubọ jẹ kawọn araalu ji giri si ojuṣe wọn lasiko eto idibo to n bọ ni 2023 yoo tẹsiwaju, o ni gbogbo ọna ni ajọ INEC n ṣan lati fẹsẹ ijọba demokiresi rinlẹ lorileede yii.

Leave a Reply