Babade foju bale-ẹjọ l’Ọrẹ, oṣiṣẹ kootu lo lu lalubami

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

 

 

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti wọ oniṣowo epo kan ti wọn porukọ rẹ ni Tọpẹ Babade lọ sile-ẹjọ Majisreeti to wa niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, lori ẹsun lilu awọn oṣiṣẹ kootu kan lalubami lasiko ti wọn wa lẹnu isẹ oojọ wọn.

Olujẹjọ ọhun ni wọn lo lu oṣiṣẹ kootu kan, Oluwaniyi Adebanji, atawọn meji mi-in nilukulu nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ tijọba ran wọn lagbegbe kan ti wọn n pe ni Area Mother, niluu Ọrẹ, ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ ọjọ kẹwaa, oṣu kẹta, ọdun ta a wa yii.

Ọlọpaa agbefọba, Jimoh Amuda, ni iwa ti olujẹjọ ọhun hu lodi si abala ọtalelọọọdunrun din mẹrin (356) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Amofin A. J. Agbor to jẹ agbẹjọro olujẹjọ bẹbẹ fun beeli onibaara rẹ niwọn igba ti ofin kò ti ta ko beeli iru ẹsun ti wọn fi kan an.

Adajọ O. A. Ọmọfọlarin ni ko boju mu kile-ẹjọ gba beeli olujẹjọ nigba ti ọkan ninu awọn to lu lalubami ṣi wa lẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun nile-iwosan.

O paṣẹ ki ọkunrin oniṣowo naa ṣi wa lahaamọ awọn ọlọpaa titi dọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹta, ọdun 2021.

 

Leave a Reply