Babalawo ti wọn ka ori oku mọ lọwọ ni oogun ẹfọri-tuulu loun fẹẹ fi i ṣe

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogoji kan to yan iṣẹ babalawo laayo, Sẹmiu Oyewọ, ti sọ pe oun ko mọ pe o lodi sofin tabi o nijiya labẹ ofin lati maa gbe ori oku gbigbẹ kaakiri.

Sẹmiu, ẹni to sọ pe oun jogun iṣẹ awo lọwọ baba oun to ti doloogbe ni ọwọ awọn ọlọpaa tẹ loju ọna Ifẹ si Ibadan lọjọ keje, oṣu keje, ọdun yii, pẹlu ori oku gbigbẹ kan lọwọ rẹ.

Aago mẹjọ alẹ ọjọ naa ni awọn ọlọpaa da mọto Honda Accord alawọ dudu to ni nọmba AGL 412 CD ti Sẹmiu n gbe lọ si Ifẹ duro.

Lasiko ti wọn n ṣayẹwo mọto rẹ ni wọn ba ori oku gbigbẹ naa atawọn oogun mi-in nibẹ. O jẹwọ fun awọn ọlọpaa pe ọkunrin kan, Ige, toun naa n ṣe iṣẹ babalawo niluu Apomu lo ta ori naa fun oun.

Nigba ti kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, Wale Ọlọkọde, n ṣafihan Sẹmiu, to n gbe ni Alamọle, niluu Ileefẹ, afurasi yii ṣalaye pe oogun ori-tuulu loun fẹẹ fi ori oku naa ṣe fun onibaara oun kan niluu Eko.

Sẹmiu sọ pe oun ko lo ẹya-ara eeyan ṣe oogun fun ẹnikẹni ri, ṣugbọn nigba toun ka a ninu iwe akanti oogun toun jogun lọdọ baba oun pe ori oku gbigbẹ atawọn eroja kan le ṣiṣẹ fun ori-tuulu lo jẹ koun gba iṣẹ naa.

O ni nigba toun sọ fun Ige ni iyẹn sọ foun pe awọn birikila maa n ri ori-oku gbigbẹ ti wọn ba lọọ gbẹ ipilẹ ile. Ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira lo ni Ige ta ori naa foun ṣugbọn ẹgbẹrun lọna marundinlọgbọn naira loun san fun un lọjọ toun lọọ gbe e.

Yatọ si oogun iwosan to ni oun n ṣe, o ni oun tun maa n ṣe oogun awọro ati bẹẹ bẹẹ lọ fawọn eeyan.

Amọ ṣa, Ọlọkọde ti sọ pe laipe ni afurasi naa yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply

%d bloggers like this: