Bi ẹnikẹni ba wa ninu iṣoro ijinigbe tabi wahala mi-in l’Ogun, awọn nọmba yii ni kẹ ẹ pe…

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Pẹlu bi ijinigbe ṣe di nnkan ojoojumọ lorilẹ-ede yii, Kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ke si awọn eeyan kaakiri ipinlẹ yii pe ki wọn mu aabo ara wọn lọkun-unkundun, nitori iṣẹ aabo ti kuro ni ti ọlọpaa nikan, ki kaluku foju ṣọri ni.

Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi ṣọwọ s’ALAROYRE lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, nibi to ti sọ pe awọn ajinigbe ti bẹrẹ si i da ọgbọn mi-in bayii, ọgbọn naa si ni gbigbe mọto ero si ẹba ọna fawọn eeyan to ba fẹran ki wọn maa wọ ọkọ sọọlẹ.

O ni awọn eeyan bii mẹrin yoo ti wa ninu mọto ọhun ti wọn yoo jẹ ajinigbe, ṣugbọn ẹni to fẹẹ wọ mọto sọọlẹ yii ko ni i mọ, to ba ti n wọle bayii ni wọn yoo gbe e gba inu igbo lọ, wọn yoo si maa beere owo nla lọwọ awọn eeyan rẹ ki wọn too tu u silẹ.

Alukoro kilọ fawọn eeyan to ba n wọ ọkọ sọọlẹ pe ki wọn yee ṣe bẹẹ, o ni ki wọn maa lọ si ibudokọ lọọ wọkọ ni.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa gba awọn omọleewe giga nimọran, paapaa awọn to jẹ wọn ko gbe inu ọgba ileewe, to jẹ wọn gba ile sita ni. Wọn ni ki wọn ri i pe wọn n ṣọ ara wọn daadaa nipa ibi ti wọn ba n lọ, ati asiko ti wọn n rin, ki wọn ma foru rin bii ọrọ nitori ewu ijinigbe.

Yatọ si eyi, Kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Ogun ni kawọn akẹkọọ ri i daju pe wọn ni nọmba ẹrọ ibanisọrọ awọn ọlọpaa agbegbe ati DPO ibi ti wọn ba wa, ki wọn ma si ṣe jẹ ko pẹ ki wọn too pe bi wọn ba kẹẹfin awọn ti irin wọn mu ifura dani lori ọkada, ninu mọto tabi ti wọn n fẹsẹ rin.

Bi ẹnikẹni ba wa ninu iṣoro ijinigbe tabi wahala mi-in, eyi ni awọn nọmba ti ileeṣẹ ọlọpaa Ogun fi sita lati pe fun iranlọwọ oju ẹsẹ: 08081770416, 08081770419 ati 08066611771.

Leave a Reply