Bọlaji Ọrẹagba di ọga agba tuntun fun LASTMA l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Oluṣọla Sanwo-Olu, ti buwọ lu iyansipo Ọgbẹni Bọlaji Ọrẹagba gẹgẹ bii ọga agba ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ loju popo nipinlẹ Eko, LASTMA.

Atẹjade kan lati ọfiisi Olori awọn oṣiṣẹ ọba ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Hakeem Muri-Okunọla,  sọ pe ayipada ati iyansipo naa waye lati tubọ mu itẹsiwaju ati igba ọtun ba lilọ bibọ ọkọ nipinlẹ Eko, paapaa lẹka ajọ Lagos State Traffic Management Authority.

Ọgbẹni Ọrẹagba ti wa nipo Igbakeji adari fun ẹka lilọ bibọ ọkọ nileeṣẹ LASTMA ki wọn too yan sipo ọga aga yii.

Oye to ga lo ni ninu imọ abojuto ọkọ, Transport Planning and Management, lati Fasiti Eko. Lati ọjọ kẹjọ, oṣu kejila, ọdun 1993, lo ti wọṣẹ ọba sileeṣẹ LASTMA.

Tẹ o ba gbagbe, Ọgbẹni Ọlajide Oduyọye lo ti wa nipo ọga agba LASTMA, ṣaaju iyansipo Ọrẹagba yii.

Leave a Reply