Derrick fada ge ọwọ ọmọbinrin yii bọ nitori ko gba ko fipa ba a lo pọ

Ko si idi kan fun ọmọdebinrin yii, Evelyn Namasopo, ọmọ ọdun mẹrindinlogun (16)lati padanu ọwọ rẹ to ge kuro yii, ṣugbọn ọmọ naa ti di ọlọwọ kan bayii o, ọkunrin kan to fẹẹ fipa ba a lo pọ to kọ fun lo fada ge ọrun ọwọ ẹ bọ, to tun ṣa a ladaa kaakiri ara lọjọ kẹrin, oṣu kẹrin, ọdun 2021 yii.

Orilẹ-ede Uganda niṣẹlẹ yii ti waye, ẹni to fẹẹ fipa ba a lo pọ naa ni wọn pe orukọ ẹ ni Derrick Kuloba, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn. Abule Nabooti, lagbegbe Bududa, ni wọn lo n gbe. Nigba ti Evelyn n ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ ni kootu kereje ti wọn gbe ẹjọ naa lọ, o ni mama oun ni ara rẹ ko ya ti wọn da duro sọsibitu.

Ọdọ iya naa lo ni oun ti kuro lọjọ yii, toun fẹẹ lọọ gbe ounjẹ ti yoo jẹ wa nile, koun si mu aṣọ mi-in dani fun un. O ni nibi toun ti n lọ sile ni Derrick ti yọ soun lọna igbo toun n gba, o mu ada lọwọ, o si bẹrẹ si i le oun lọ.

Ọmọbinrin yii sọ pe bo ṣe ba oun lo paṣẹ pe koun bọra sihooho, nitori oun fẹẹ ṣere oge pẹlu oun. Evelyn loun ko gba fun ọkunrin naa, oun ko si bọ aṣọ oun. O ni bi Derrick ṣe sọ pe boun ko ba ti gba, oun yoo ṣa oun pa niyẹn.

Nigba naa lo si gbe ada soke bọmọ yii ṣe wi, lo fẹẹ fi bẹ ori oun danu. Evelyn loun tete fọwọ ọtun oun gba ada naa danu, bẹẹ lọwọ naa ṣe ge kuro, ti ọkunrin yii si bẹrẹ si i ṣa oun lẹsẹ ati kaakiri ara.

Loootọ ni wọn ri Derrick mu lẹyin iwa to hu naa, ṣugbọn wọn ti da a silẹ lagọ

ọ ọlọpaa laipẹ rara. Eyi gan-an lohun to n dun ọmọbinrin to ṣi n jẹrora yii ju, to fi sọ pe kawọn eeyan dide si ọrọ ohun, ki wọn ba oun wa idajọ ododo.

Akẹkọọ ni Evelyn, ko rọwọ kọwe mọ, bẹẹ ni iya rẹ ko rowo ọsibitu to ti n gba itọju san. Bi wọn yoo ṣe ri Derrick mu, ti yoo jẹjọ igbiyanju lati fipa ba ni lo pọ, ati igbiyanju lati paayan ni ọmọ yii ati iya rẹ n bẹbẹ fun bayii, wọn ni ki gbogbo aye waa gbeja awọn.

Leave a Reply