Ẹ gba wa o! Bawọn fulani ṣe n ya wọlu Iwo lewu fun wa o – Awọn ọdọ

Florence Babaṣọla

 

Agbarijọpọ awọn ọdọ niluu Iwo, ‘Iwoland Concerned Youths’, ti kegbajare pe ilu naa ti wa ninu ewu pupọ latari bi ọba wọn, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ṣe kede laipẹ yii pe ki awọn Fulani ti wọn ba nifẹẹ lati maa gbe inu ilu maa bọ niluu Iwo.

Lasiko ipade awọn oniroyin ti wọn ṣe ni Aarẹ wọn, Taiwo Ewonda, ti sọ pe ijọba ipinlẹ Ọṣun nilo igbesẹ ni kiakia lori ọrọ aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan ilu Iwo.

O ṣalaye pe lati ọjọ kọkandinlogun, oṣu keji, ọdun yii, ti Oluwoo ti kede pe aaye wa fawọn Fulani niluu Iwo ni oniruuru awọn Fulani ti n ya wọnu ilu naa, eleyii to si ti da ibẹrubojo sọkan awọn araalu bayii.

 

Ewonda sọ pe loootọ ni anfaani wa fun gbogbo ọmọ orileede yii ninu iwe ofin ilẹ wa lati rin tabi gbe nibikibi to ba wu wọn, sibẹ, irufẹ ominira bii eleyii ko gbọdọ sọ awọn alejo di ẹru wuwo fun awọn oniluu.

O fi kun ọrọ rẹ pe tijọba ko ba tete gbe igbesẹ lori bi awọn Fulani ṣe n wọnu ilu Iwo lọsan-loru bayii, ọrọ naa yoo bẹyin yọ nigbakuugba, eleyii to si le da omi alaafia agbegbe naa ru.

Gẹgẹ bo ṣe wi, gbogbo awọn ọdọ ilu naa ni wọn ko ṣetan lati jẹ ki ohunkohun pagi dina ifọkanbalẹ to ti wa niluu Iwo latọjọ pipẹ, wọn ni awọn takete si ipe ti Oluwoo fi ranṣẹ sawọn Fulani ti wọn n fojoojumọ wọlu naa bayii.

Leave a Reply