Eeyan mẹrin ku ninu mọlẹbi kan, meji dero ileewosan, eefin jẹnẹretọ lo pa wọn ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

O kere tan, eeyan mẹrin ti ku ninu mọlẹbi kan, ti meji si dero ileewosan, lagboole Ojomu, niluu Sanmora, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, ipinlẹ Kwara, eefin jẹnẹretọ lo pa wọn mọju.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, ni awọn mọlẹbi kan ti wọn de lati ilu Eko fun ayẹyẹ ọdun Ileya, niluu Sanmora, ni mẹrin ninu wọn ti ku, ti meji si wa lẹṣẹ-kan-aye, ẹṣẹ-kan-ọrun latari pe wọn tan ẹrọ amunawa sinu ile ti wọn fi sun lalẹ, eyi lo mu ki eefin jẹnẹretọ naa pa wọn lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, mọju Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii.

Wọn ti ko awọn oku ọhun lọ si yara igbooku-si nileewosan ijọba tilu Ọffa, ti wọn si ko awọn meji ti wọn o ti i ku lọ si ọsibitu fun itọju to peye.

Ni nnkan bii aago meje owurọ, Ọjọruu, Wẹsidee, ni iya arugbo kan to n gbe agboole kan naa pẹlu awọn oloogbe yii fẹẹ lọọ ki wọn, nigba to wọle to ba oku wọn rẹkẹrẹkẹ nilẹ lo figbe ta.

Awọn tọrọ naa ṣoju wọn sọ pe DPO agọ ọlọpaa ilu Agbamu, Igbasan Owoyẹmi John, wa lara awọn ti wọn jọ ko oku awọn mọlẹbi ọhun jade kuro ninu ile. Awọn to ku ni ọkọ, iyawo, ọrẹ iyawo, ati ọmọ ọrẹ wọn kan to tẹle wọn waa ṣọdun lati ilu Eko.

Alukoro Ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o si rọ awọn olugbe ipinlẹ Kwara lati maa fi ọrọ aabo siwaju ohunkohun ti wọn ba fẹ ṣe e.

Leave a Reply