Ẹgbẹ Afẹnifere ṣabẹwo si Tinubu

Jọkẹ Amọri

Ẹgbẹ Afẹnifẹre, leyii ti olori wọn, Oloye Ayọ Adesanya, ṣiwaju, ti ṣabẹwo ṣe ara ya si Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ni ile rẹ to wa ni Bourdilon, niluu Ikoyi, nipinlẹ Eko, ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Lasiko abẹwo naa ni wọn ba Aṣiwaju yọ pe o ja ajabọ lọwọ aisan to gbe e kuro niluu fun ọpọlọpọ ọjọ yii, to si pada sile rẹ lalaafia..

Lara awọn to kọwọọrin pẹlu Baba Adesanya lọ sile Aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC naa ni Igbakeji olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Ọba Ọlaitan Ọladipọ, Oloye Ṣupọ Ṣhonibarẹ, igbakeji ọga ọlọpaa nilẹ wa tẹlẹ, Tunji Alapinni, ọmọ Oloye Adebanjọ, Ṣade, atawọn mi-in.

Leave a Reply