Faith Adebọla, Eko
Igbimọ alakooso apapọ fun ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, APC, ti tu eto akoso wọn ni apapọ, gbogbo ipinlẹ, ẹkun (zone), ati ibilẹ pata jake-jado orileede yii, titi kan Abuja ka, bẹẹ ni wọn tun faṣẹ si i pe ki igbimọ afun-n-ṣọ to n tukọ ẹgbẹ naa ṣi maa ba iṣẹ niṣo fun oṣu mẹfa si i.
Nibi ipade kan tigbimọ alakooso apapọ naa ṣe l’Abuja, eyi ti pupọ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ pesẹ si, tawọn mi-n si darapọ lori atẹ ayelujara lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni wọn ti ṣepinnu ọhun. Aarẹ orileede wa, Muhammadu Buhari lo ṣalaga ipade naa.
Lara awọn to wa nipade naa ni Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, awọn gomina ẹgbẹ APC ati awọn ijoye pataki ẹgbẹ naa.
Gomina ipinlẹ Kaduna, to bawọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade sọ pe awọn ti fontẹ lu u pe ki igbimọ afun-n-ṣọ ti Gomina Mai Buni tipinlẹ Yobe n tukọ rẹ lo oṣu mẹfa mi-in si i lẹyin ti saa oṣu mẹfa akọkọ ti wọn yọnda fun un ti pari.
O ni eyi yoo mu ki igbimọ naa tubọ ṣiṣẹ lori pipari awọn fa-a-ka-ja-a gbogbo to ṣi ku ninu ẹgbẹ, ki wọn si ṣeto apejọ gbogbogboo, nibi ti wọn yoo ti yan awọn igbimọ alakooso tuntun.
Ipinnu mi-in ti wọn ṣe nibi ipade naa ni ti jijawee kuro-lẹgbẹ-wa fun Ntufam Hillida Eta, ẹni to ti figba kan jẹ Igbakeji alaga apapọ ni ẹkun Guusu, latari bi ọgbẹni naa ṣe kọ lati jawọ ninu ẹjọ to pe ta ko igbimọ-afun-n-ṣọ to wa lode yii.