Ẹsun ayederu iwe-ẹri: Awọn ẹgbẹ kan ni Tinubu ko yẹ lati dupo aarẹ

Ọrẹoluwa Adedeji
Pẹlu ariwo to n lọ lọtun-un losi bayii lori awọn ohun ti oludije sipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, kọ sinu fọọmu rẹ to fi ranṣẹ si ajọ eleto idibo nipa awọn ileewe to lọ, ọkunrin oloṣelu naa yoo ni lati ṣalaye rẹpẹtẹ kawọn eeyan too le gba a gbọ pe ododo ọrọ lo n ṣọ lori awọn ohun to sọ pe o ṣẹlẹ si iwe-ẹri rẹ.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to lọ lọhun-un, iyẹn ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfa, ni ọkunrin naa fi fọọmu rẹ ranṣẹ sajọ eleto idibo lẹyin ti ẹgbẹ ti yan an gẹgẹ bii ẹni ti yoo dije lorukọ wọn.
Ṣugbọn ni Furaidee, ọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja yii, ni ariwo deede gba ilu, ti awọn eeyan si n gbe fọọmu naa kiri ori ayelujara.
Ohun ti Tinubu kọ sinu fọọmu ọhun ni pe oun ko lọ si ileewe alakọọbẹrẹ tabi girama kankan, ṣugbọn o kọ ọ sibẹ pe oun lọ si yunifasiti kan, nibi ti oun ti gba oye nipa eto ọrọ aje ati isakoso rẹ (Business AND ADMINISTRATION), bo tilẹ jẹ pe ko fi orukọ ileewe to ti gba oye yii si i. Ọdun 1979 lo kọ sibẹ pe oun jade nileewe yii.
Bakan naa ni Tinubu kọ ọ sinu fọọmu ọhun pe lasiko kan ti oun sa lọ si ilu oyinbo nitori pipa ti wọn fẹẹ pa oun laye ijọba Abacha ni awọn ṣọja aimọ kan ya wọ ile oun, ti wọn jo o, ti wọn si jo gbogbo iwe-ẹri oun mọ inu ile naa, idi niyi ti oun ko fi ri iwe ẹri naa ko silẹ.
Eyi lawọn to ri fọọmu naa koro oju si ti, wọn si n beere pe bawo ni eeyan kan yoo ṣe jade, ti yoo ni oun ko lọ si ileewe alakọọbẹrẹ, oun ko si lọ si girama, to si waa lọ si ileewe giga yunifasiti.
Ohun to mu ọrọ naa kọ awọn eeyan lominu, ti wọn si fi gbagbọ pe ejo lọwọ ninu lori ọrọ naa ni pe ni ọdun 1998, nigba ti Tinubu yoo fọwọ si fọọmu ajọ eleto idibo naa, iyẹn lasiko to fẹẹ ṣe gomina ipinlẹ Eko, o fọwọ si fọọmu naa pe oun lọ sileewe alakọọbẹrẹ kan ti wọn n pe ni ST. Paul, Arolọya, niluu Eko, ati Children Home School, niluu Ibadan. Bẹẹ lo ni oun lọ si ileewe girama kan ti wọn n pe ni Government College, niluu Ibadan, ati Richard Dalley College, ni Chicago, lorileede Amẹrika lọdun 1969-71. Bẹẹ lo ni oun lọ si awọn ileewe giga fasiti kan niluu oyinbo. University of Chicago, ni 1972-76, ti oun si gba oye imọ nipa ọrọ aje (Bsc Economics). Bakan naa lo ni oun lọ si Chicago State University, lọdun 1977-1979, nibi ti oun ti gboye nipa okoowo ati isakoso rẹ.
Asiko naa ni ogbontarigi agbẹjọro nni, Oloogbe Gani Fawẹhinmi, gbe Tinubu lọ si kootu, to si sọ nile-ejọ pe ayederu ni awọn iwe ti Tinubu ko silẹ pe oun ni to fẹẹ fi dupo gomina, ati pe ko lọ si aọn ileewe to sọ pe oun lọ yii. Bẹẹ ni wọn kọwe si awọn ileewe kan ninu awọn to darukọ yii niluu oyinbo, tawọn yẹn si fidi rẹ mulẹ lasiko naa lọhun-un pe ki i ṣe akẹkọọ awọn.
Wọn fa ọrọ naa titi debii pe awọn ọmọlẹyin Tinubu nigba naa doju ija kọ ọkunrin agbẹjọro yii, bẹẹ ni wọn maa n lẹ ẹ loko kiri to ba ti jade ni kootu, ti wọn si n sọ pe ki Fawẹhinmi fi ọkunrin oloṣelu naa silẹ.
Iwadii ti wọn ṣe nigba naa fi han pe Tinubu ko lọ si awọn ileewe to darukọ yii nitori ẹgbẹ awọn akẹkọọ ileewe Government College, Ibadan, jade pe Tinubu ki i ṣe ara awọn. Nigba ti wọn si ni ko darukọ awọn ti wọn jọ lọ sileewe nigba naa, ọkunrin yii ko ri ẹnikẹni darukọ.
Bakan naa lọrọ ri nigba ti wọn de ibi to ni oun ti kawe alakọọbẹrẹ yii ni Arolọya, ti wọn ri i pe ko si ileewe kankan nibẹ lasiko ọhun, ṣọọṣi ni wọn kọ sibẹ.
Nigba ti ọrọ naa di wahala ni ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ AD nigba naa to tun ti figba kan jẹ sẹnetọ, Tokunbọ Afikuyọmi, jade sita, to ni oun loun fọwọ si fọọmu naa nigba naa, ati pe aṣiṣe ni oun ṣe.
Eyi lo ṣe jẹ pe nigba ti Tinubu yoo fọwọ si iwe ajọ eleto idibo nigba to fẹẹ ṣe gomina ipinlẹ Eko lẹẹkeji lọdun 2003, ko ṣopo kọ orukọ ileewe alakọọbẹrẹ ati girama yii si i, bẹẹ ni ko kọ orukọ ọkan ninu awọn yunifasiti yii si i.
Wọn fa ọrọ naa titi de ile-ẹjọ to ga ju lọ nigba naa, ṣugbọn wọn doju ẹjọ naa ru. Ki i ṣe pe adajọ sọ pe Tinubu jare lori awọn ẹsun iwe-ẹri yii o, ṣugbọn adajọ to dajọ naa sọ pe awọn to gbe ẹjọ wa ko ṣeto iwe ẹjọ naa bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ, bẹẹ ni wọn ko pe awọn to yẹ ki wọn pe mọ ẹjọ naa gẹgẹ bii olujẹjọ. Lori eleyii ni wọn fi da ẹjọ naa nu, wọn ko tilẹ mẹnu ba ọrọ ayederu iwe-ẹri ti wọn tori ẹ ba a ṣẹjọ lasiko naa.
Ṣugbọn ni bayii, ẹgbẹ oṣelu kan ti wọn n pe ni Action Peoples Party (APP), ti jade sita, wọn ni bi ilẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ba ti n mọ bayii, ile-ejọ ni awọn n gba lọ lati pe oludije ti ẹgbẹ APC fa kalẹ, Bọla Tinubu, lẹjọ. Wọn ni eyi ko sẹyin awọn ipaṣipayo to wa ninu awon iwe ẹri to kọ silẹ pe oun ni atawọn eyi to fi orukọ wọn si i ninu iwe ajọ eleto idibo.
Alaga ẹgbẹ ọhun, Uche Nnadi, lo sọrọ naa lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, o ni ẹgbẹ naa ni awọn ẹri to fẹsẹ mulẹ lati pe Tinubu lẹjọ.
Ọkunrin naa ni ninu orukọ awọn oludije ti ajọ eleto idibo gbe jade, Tinubu ko kun oju oṣuwọn lati dupo aarẹ orileede wa pẹlu bo ṣe purọ pe oun ko lọ sileewe alakọọbẹrẹ, bẹẹ loun ko lọ si ileewe girama.
Wọn ni Tinubu ti dẹṣẹ ibura eke ati irọ pipa pẹlu bo ṣe kọ lati lo orukọ awọn ileewe to ti kọkọ sọ pe oun lọ nigba to n fọwọ si fọọmu ajọ eleto idibo lọdun 1998 to fẹẹ dupo gomina ipinlẹ Eko.
Wọn ni eyi to ṣẹṣẹ fọwọ si fun ajọ eleto idibo lasiko to fẹẹ dupo aarẹ yii yatọ si eyi to ti fọwọ si lọdun 2007 to ti sọ pe oun lọ sileewe alakọọbẹrẹ ati girama.
Ki i ṣe ẹgbẹ yii nikan lo ti jade sita bayii o, bakan naa ni ẹgbẹ ajafẹtọọ ọmọniyan kan ti wọn n pe ni Centre for Reform and Public Advocacy, ti fun ọga ọlọpaa patapata lorileede wa ni wakati mejidinlaaadọta pere lati mu Aṣiwaju Bọla Tinubu, ki wọn si ba a ṣẹjọ ọdaran pẹlu bo ṣe ko awọn ayederu iwe-eri silẹ lati fi dupo aarẹ.
Ẹgbẹ yii si ti n dunkooko pe ti ọga ọlọpaa yii ba kọ lati gbe igbesẹ, awọn yoo gbe ẹjọ dide si oun naa lati kan kan nipa fun un lati mu Tinubu ti akoko ti awọn darukọ yii ba ti tẹnu bọpo.
Agbẹjọro fun awọn ẹgbẹ yii, Agu Kalu, lo sọrọ naa ninu ipade awọn oniroyin kan to ṣe niluu Abuja lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to ṣẹṣẹ pari yii.
Ṣugbọn oludari awọn agbẹjọro ẹgbẹ to n ri si si ipolongo ibo fun Tinubu ti sọ pe ẹru ko ba awọn lori gbogbo idunkoooko mọ ni yii. O ni Tinubu ko ṣe ohunkohun to lodi si ofin ilẹ wa, o ni awọn n duro de gbogbo awọn ti wọn fẹẹ gbe ẹjọ dide naa, awọn yoo si da wọn lohun bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.
Titi di ba a ṣe n sọ yii, ọrọ naa ko ti i rodo lọọ mumi, nitori oriṣiiriṣii awuyewuye lo ti n lọ lori ọrọ yii, bo tilẹ jẹ pe ajọ eleto idibo tabi ẹgbẹ APC ko ti i wi kinni kan lori rẹ.
Ohun ti ọpọ awọn alatilẹyin Tinubu n sọ ni pe ẹgbẹ oṣelu PDP lo wa nidii ọrọ yii, nitori wọn ti mọ pe awọn ko le rọwọ mu lasiko idibo to n bọ yii. Eyi ni wọn si ṣe n wa gbogbo ọna lati ri i pe wọn ba Tinubu lorukọ jẹ.
Bi nnkan ṣe wa yii, bi Tinubu ko ba jajabọ ninu ẹjọ naa, afaimọ ko ma jẹ Rotimi Amaechi, iyẹn gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ to tun ṣẹṣẹ kuro nipo minisita feto irinna ọkọ ni yoo dije gẹgẹ bii aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC.
Adura ti ọpọ awọn ololufẹ Tinubu n gba fun un bayii ni pe ki Ọlọrun jẹ ki aago yii ko re kọja lori rẹ bo ṣe n re kọja latẹyinwa. Ṣugbọn awọn iṣẹlẹ to ba ṣẹlẹ ni awọn ọjọ diẹ sasiko yii ni yoo sọ ibi ti ọrọ naa yoo ja si.

Leave a Reply