Eyi nidi ti mo fi kọju ija sawọn ọmọọta to tọrọ owo lọwọ mi-Ogogo

Monisọla Saka
Gbajugbaja oṣere tiata nni, Taiwo Hassan, ti pupọ awọn eeyan mọ si Ogogo, ti sọrọ lori ija kan to ṣẹlẹ laarin oun atawọn ololufẹ ẹ niluu Ilaro, nipinlẹ Ogun.

Ninu fidio kan to n ja ran-in ran-in lori ẹrọ ayelujara ni oṣerekunrin yii ti n wọdimu pẹlu ọkunrin kan laarin ero, lẹyin naa lo ta kọṣọ sinu ọkọ rẹ, to wa si wa a kuro nibẹ.

Nigba to gbe fidio naa sori afẹfẹ, Ogogo gba ori Instagraamu rẹ lọ lati ṣalaye idi tọrọ fi ri bẹẹ.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o lawọn ololufẹ oun atawọn kan ni wọn waa ba oun, ti wọn si beere iye owo kan ti agbara oun ko ka lọwọ oun.
O ni bo ṣe jẹ pe oun fun wọn ni gbogbo owo to wa lọwọ oun, ọkan ninu awọn ti wọn sọ pe awọn n ṣe toun yii tun bẹrẹ si i fagidi fa oun laṣọ, eyi lo si fa nnkan ti oun ṣe yẹn.
Taiwo Hassan ni kawọn bulọga ti wọn jẹ oniroyin ori afẹfẹ too ri eleyii maa gbe kiri loun ṣe ṣalaye bi ọrọ naa ṣe jẹ.

O ni, ”Ilaro to jẹ ilu mi gangan ni mo lọ lati lọọ ṣabẹwo si iṣẹ akanṣe kan, ṣadeede lawọn ọmọkunrin kan ti mi o mọ ri yọ si mi, ti wọn si n ki mi gẹgẹ bi wọn ṣe maa n sa ori wa.

“Ariwo to gba ẹnu wọn kan ni, ‘a maa n wo fiimu yin, fun wa lowo, iwọ la n wo ni gbogbo igba kekere wa’… Bẹẹ, gẹgẹ bii oṣere tiata, gbogbo nnkan yii la n gbọ lojoojumọ.

“Gbogbo owo to wa lọwọ mi ni mo ko fun wọn, bi ọkan ninu wọn ṣe fa mi lagbada pada niyẹn, lo ba n beere iye tagbara mi o le ka. Mo ni ko fi mi silẹ, o ni ki n ṣe ohun ti mo ba fẹ ṣe… Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ niyẹn”.
Ogogo waa rọ awọn ololufẹ wọn lati jawọ nidii a n pe le awọn irawọ oṣere atawọn gbajumọ lori fun owo, nitori iru iṣẹ ilu-mọ-ọn-ka ti wọn n ṣe.

O ni, “Ṣe ẹ maa n fun ẹnikẹni lowo lati ṣiṣẹ yin, abi nitori iṣẹ ti ẹ n ṣe? Bẹẹ kọ. Iṣẹ tiwa naa ni, ẹ fifẹ gba gbogbo ohun ta a ba mu kalẹ nigba ta a ba fun yin. Ẹ ma gbagbe pe, ẹlẹṣẹẹ kikan(boxer) ti mo figba kan jẹ ri o ti i kuro lara.

Leave a Reply