Ẹsun ole ati biba dukia ijọba jẹ ni wọn tori ẹ mu awọn eleyii ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Afurasi mẹrindinlọgbọn lo wa ni pampẹ ileeṣẹ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, nipinlẹ Kwara bayii, ẹsun ti wọn fi kan wọn ni jiji awọn waya ina ati biba dukia ijọba jẹ.

Ọga agba NSCDC ni Kwara, Ọgbẹni Makinde Iskil Ayinla, ṣalaye ninu atẹjade kan ti Alukoro ajọ naa, Babawale Zaid Afọlabi, gbe sita l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, pe Ọjọruu, Wẹsidee, oun gba ipe lati ẹka to n fimu finlẹ nileeṣẹ NSCDC nipa bawọn ọbayeje naa ṣe lọ n ji ẹru ijọba ko lagbegbe Ararọmi, Akata Tankẹ, niluu Ilọrin.

Ayinla ni loju ẹsẹ loun paṣẹ fawọn ikọ to n gbogun ti biba dukia ijọba jẹ lati tọpinpin awọn afurasi naa.

O ni awọn pada le wọn de ibuba wọn, ṣugbọn mẹta lara awọn afurasi naa; Tanko, Bashir L.K ati Nafiu sa lọ, wọn si pa ọkada Bajaj ti wọn fi n jale atawọn waya ina ti wọn ti ji ko ti.

Ileeṣẹ NSCDC ni awọn mu ẹni to gba awọn afurasi mẹta to sa lọ naa sile rẹ, Sulieman Abdullahi, pẹlu awọn afurasi mẹẹẹdọgbọn.

Ayinla ni iwadii awọn fi han pe Suleiman, ẹni to n ṣe bii ẹni to n ṣa nnkan kiri lori aatan, lo ko awọn afurasi yooku sodi lati maa dọgbọn ṣe bii tiẹ, ti wọn si n ba awọn ohun amayedẹrun tijọba ṣe fun araalu jẹ, wọn si n ji wọn ko.

O ni igba tawọn lọọ yẹ ile Sulieman wo, awọn ba waya, maṣinni ti wọn fi n pọnbu omi mẹfa, ẹrọ amunawa kan, kọmputa alagbeeka mẹta, ọpọlọpọ foonu, agbada to n pese ina to n lo itansan oorun (Solar Panel) meji atawọn nnkan mi-in tawọn fura si pe wọn ji ko.

O tẹsiwaju pe gbogbo ẹru naa ti wa ni olu ileeṣẹ awọn, idaniloju wa pe ọwọ yoo tẹ awọn afurasi to sa lọ.

O waa ṣekilọ fawọn ọdọ lati ma lọwọ ninu iwa ọdaran nipa biba dukia ijọba jẹ tabi jiji ohun to yẹ ko jẹ anfaani fun araalu.

Leave a Reply