Ẹyin minisita, tẹ ẹ ba fẹẹ dupo oṣelu, ẹ kọwe fiṣẹ yin silẹ-Buhari

Jokẹ Amọri
Ni Ọjọruu, Wesidee, ọsẹ yii, ni Aare ilẹ wa, Muhammadu Buhari, pasẹ fun gbogbo awọn oloṣelu to n ba a ṣiṣẹ pe gbogbo ẹni to ba fẹẹ dupo kan tabi omi-in ninu wọn gbọdọ kọwe fi iṣẹ wọn silẹ kiakia. Eyi kan awọn minisita to n ba a ṣiṣẹ atawọn to dipo oṣelu mi-in mu.
Lasiko ti wọn n ṣepade igbimọ apaṣẹ ilẹ wa lo sọrọ naa. Minisita feto iroyin ati aṣa, Alaaji Lai Muhammed, lo sọrọ naa fawọn oniroyin lẹyin ipade naa pe gbogbo awọn oloṣelu to n ba ijọba ṣiṣẹ ti wọn si nifẹẹ lati dije dupo kan tabi omi-in ninu idibo ọdun to n bọ, gbọdọ kọwe fipo ti wọn wa silẹ, ki wọn si gbaju mọ oṣelu ti wọn fẹẹ ṣe.
Lara awọn ti ọrọ yii kan ninu awọn to ti gba fọọmu lati dupo aare ilẹ wa ni Minisita fun igbokegbodo ọkọ nilẹ wa, Rotimi Amaechi, Minisita fun iṣẹ ṣiṣe ati igbani ṣiṣẹ, Chris Ngige, Gomina ipinlẹ Akwa Ibom telẹ to tun jẹ minisita fun ọrọ Naija Delta, Godswill Akpaibo, Ogbonaya Onu toun jẹ minisita fun sayẹnsi ati imọ ẹrọ, Abaubakar Malami to jẹ minisita feto idajọ nilẹ wa. Minisita fọrọ obinrin, Paulline Tallen, toun naa fẹẹ dupo sẹnetọ lagbegbe rẹ.
Bakan naa ni Minisita to wa fun awọn ohun alumọọni ilẹ wa, Uche Ogar atawọn mi-in bẹẹ.
O to ọjọ mẹta ti ariwo ti n lọ lori boya o yẹ ki awọn eeyan naa fipo wọn silẹ ki wọn too dije dupo mi-in. Ṣugbọn pẹlu aṣẹ ti Buhari pa yii, awọn eeyan naa gbọdọ fi ipo wọn silẹ kiakia ti wọn ba mọ pe loootọ laọn fẹẹ dije.

Leave a Reply