Fulani darandaran fibọn ṣẹru ba iyawo ile, lo ba fipa ba a lo pọ ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ yii, nile-ẹjọ Majistreeti kan to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo paṣẹ ki wọn sọ Fulani darandaran kan, Hassan Namusa, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, sahaamọ fẹsun pe o fibọn ṣẹru ba iyawo ile kan, to si fipa ba a lo pọ ni Kaiama, nijọba ibilẹ Kaiama, nipinlẹ Kwara.
Agbefọba, Insipẹkitọ Issa Abubakar, sọ fun ile-ẹjọ pe afurasi Fulani darandaran ọhun yọbọn si iyawo ile naa, pe ko sun gbalaja ni tipa-tipa, to si fi tipatikuuku jẹ dodo rẹ, eyi to ta ko awọn abala kan ninu iwe ofin ilẹ wa, fun idi eyi, ki adajọ ma boju aanu wo o.
Onidaajọ Aminat Issa, paṣẹ pe ki wọn fi afurasi naa sahaamọ, o sun idajọ si ọjọ kẹrinla, oṣu Keje, ọdun yii.

Leave a Reply